--Advertisement--
Advertisement

Ǹjẹ́ ààrẹ orílẹ̀ èdè Senegal sọ pé ìwà orílẹ̀ èdè Faransé sí Senegal kò dára?

Tí ó bá ń lo àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media) ní wákàtí mejidinlaadọta sẹhin, ó ṣeé ṣe kí ó ti wo fídíò tí ó safihan Bassirou Diomaye Faye, ẹni tí orílẹ̀ èdè Senegal yàn laipẹ gẹ́gẹ́bí Ààrẹ níbi tí ó ti ń sọ̀rọ̀ sì orílẹ̀ èdè Faransé (France).

Fídíò yìí-èyí tí àwọn ènìyàn ti pín ni ori àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní Afíríkà ni àwọn ènìyàn tí pín ní orí Tiktok, X (tí a mọ sí Twitter tẹ́lẹ̀), Facebook, LinkedIn àti WhatsApp (Wasapu).

“Àsìkò tó tí orílẹ̀ èdè Faransé gbọ́dọ̀ dẹkùn ijokolenilọrunmọlẹ, kí wọn sì fòpin sí ìwà irẹnijẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìyà, irẹnijẹ, ikonilẹru ti fa ìyà. Ó tó gẹ́,” báyìí ni ẹni kan ṣe sọ nínú fídíò yìí.

Inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọn pín fídíò yìí dùn sí Faye, ẹni tí ó máa di Ààrẹ tí ọjọ́ orí rẹ kéré jù tí àwọn ènìyàn dibo yàn ní Afíríkà. Wọn ríi gẹ́gẹ́bí ẹni tí kò gba radarada tí orílẹ̀ èdè Faranse ń ṣe.

Advertisement

Ẹni kan tí ó ń lo X tí a mọ sí @von_Bismack, tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọn lé ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún tí wọn ń tẹle ní orí X fi fídíò náà síta ní ọjọ́ ìṣẹ́gun (Tuesday).

Láti ìgbà tí ó ti fi fídíò yìí síta, àwọn ènìyàn ẹẹdẹgbẹta ló ti fẹ́ràn ọ̀rọ̀ náà, àwọn ènìyàn ọgọrùn-ún mẹta àti mẹtalelọgbọn ló ti pín in, àwọn ènìyàn ọgbọ́n àti méjì ló ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ni wọn ti wòó. O lè rí ọ̀rọ̀ kà nípa rẹ̀ níbí yìí.

“Àsìkò tó tí orílẹ̀ èdè Faransé gbọ́dọ̀ fi Áfíríkà silẹ lọrun”…Faye ni wọn ní ó sọ ọ̀rọ̀ yìí. “Eléyìí túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn kò gba ti orílẹ̀ èdè Faransé mọ ní Afíríkà,” báyìí ni àkòrí ọ̀rọ̀ yìí ní orí X ṣe wí.

Advertisement

Ní orí Facebook, O’Kay Adedayo fi fídíò náà síta pẹ̀lú àkòrí tí ó wí pé: “Afíríkà ti jí. Kí Ọlọ́run sọ Ààrẹ Senegal tuntun. Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló kàn ní ọdún 2027. Kò sí ààyè fún àwọn olórí orílẹ̀ èdè aláwọ̀ funfun kí wọ́n má darí àwọn olórí ní Áfíríkà bí kò ṣe yẹ mọ. Àsìkò tó fún ìdàgbàsókè.”

Lórí Wasapu, àwọn ènìyàn ti pín fídíò yìí ní àìmọye ìgbà.

AYẸWO Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Ayẹwo tí TheCable,  ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe fi ye wa pé wọn yọ àwòrán yìí nínú ọ̀rọ̀ Ousmane Sonko, ènìyàn pàtàkì kan lára àwọn tí wọn wà nínú ẹgbẹ́ òsèlú alátakò ní ibi àpéjọ kan ní ọdún 2021, ní Dakar, olú ìlú orílẹ̀ èdè Senegal.

Advertisement

Èdè French ni Sonko fi bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nínú fídíò yìí. Nígbà àpéjọ yìí, ó sọ ọ̀rọ̀ nípa erongba Senegal lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ifọkanbalẹ.

Ó tún sọ ọrọ̀ nípa bí orílẹ̀ èdè Faransé kò ṣe fún àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n wà lábẹ́ ijoba wọn tẹ́lẹ̀ láyè  láti ní ìlọsíwájú.

Wọ́n fi àpéjọ yìí sórí ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn máa ń fi àwòrán tàbí fídíò sí tí a mọ sí YouTube channel of Senegal 7, ile isẹ ìròyìn kan ní orílẹ̀ èdè Faransé.

Èdè Faransé (French)ni Sonko sọ ní gbogbo wákàtí kan àti àbọ̀ tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ ní ibi àpéjọ náà. Ó túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó sọ náà lórí Twitter sí èdè Faransé.

Advertisement

TheCable tún ríi pé àwọn ènìyàn lo ohun tí a mọ sí deepfake technology láti jẹ kí ohùn rẹ dà bí ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ní èdè òyìnbó (English Language)

Ní àfikún, a ríi pé fídíò ara ọ̀rọ̀ náà ti wà lórí YouTube láti ọdún 2023.

Advertisement

ǸJẸ́ SONKO ÀTI FAYE MỌ ARA WỌN?

Sonko jẹ́ olórí Patriots of Senegal (PASTEF), ẹgbẹ́ òsèlú tí ó ti Faye lẹhin láti díje fún Ipò Ààrẹ.

Advertisement

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọn mọ nípa òsèlú gbagbọ pé “ọmọ isẹ” ni Faye jẹ́ fún Sonko. Wọn ju àwọn mejeeji sí ẹ̀wọ̀n nígbà tí ìbò Ààrẹ ń bọ̀ lọ́nà. Àmọ́, wọn tú wọn silẹ kí ó tótó ìgbà  ìdìbò.

Àmọ́sá, ilé ẹjọ́ tó ga jù ní Senegal sọ pé Sonko kò lè díje fún Ipò kankan ní àsìkò ìdìbò náà. Láti lè kópa nínú ìdìbò náà, PASTEF fa Faye silẹ kí ó díje dùn àwọn.

Advertisement

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ

Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀ èdè Faransé nínú fídíò yìí kìí ṣe Faye, Ààrẹ tí wọn ṣẹ fi ìbò yàn ní orílẹ̀ èdè Senegal. Sonko, ara àwọn olórí PASTEF ni ẹni tó sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Fídíò náà jẹ àlùmọ̀kọ́rọ́yí ọ̀rọ̀ tí Sonko sọ níbi àpéjọ kan ní ọdún 2021.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.