--Advertisement--

Ǹjẹ́ bánkí àpapọ̀  orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kéde ìfòpinsí Form A fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè òkun?

Ìròyìn tán ràn-ìn lórí ayélujára wí pé, ní ìparí ọdún yìí, bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (CBN) yóò fòpinsí lílo Form A, èyí tí máa ń e ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń kàwé ní òkè òkun láti san owó ẹ̀kọ́ wọn.

Ní ipasẹ̀ form A yìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń kàwé l’ókè òkun máa ń r’áyè san owó ẹ̀kọ́ wọn pẹ̀lú òṣùwọ̀n pasípárọ ti ìjọba, dípò àwọn tó ń ṣe pàṣípàrọ̀ dọ́là sí náírà nínú ọjà, eléyìí tí ó wọ́n ju ti ìjọba lọ.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà ní orí ayélujára ti fíbínúhàn lórí ìròyìn pé, láti oṣù kínní ọdún 2023, owó ẹ̀kọ́ tí wọn yóò máa san yóò lé si.

Advertisement

“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ìròyìn kan pé, ní oṣù kejìlá ọdún yìí, bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò fagilé Form A. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń f’ojú sọ́nà láti kàwé l’ókè òkun máa ní láti gba òṣùwọ̀n pásípáro ọ̀dọ àwọn tí wọ́n ń ṣe káràkátà owó. Ní ṣe ni ó tún burú si,” Adéwálé Adétọ̀nà, olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter), kọ èyí sí ojú òpó rẹ̀. Àwọn ènìyàn tí s’àtúnpín àtẹ̀jáde yìí ní ọ̀nà ọ̀kan dín ní ọ̀rìn-lé-ní-igba, àwọn olùmúlò míràn sì ti bu ọwọ́ ìfẹ́ lu àtẹ̀jáde yìí ní ọnà eéjìlá dín ní ọrìn lélọ́ọ̀dúnrún.

Àhesọ yìí tí ó wà l’órí ìkànnì Abẹ́yẹfò (Twitter) àti Facebook gbé àwòrán àtẹ̀jáde kan tó wá láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Manchester Metropolitan/Manchester Metropolitan Yunifásiti (Manchester Metropolitan University).

Àkòrí àtẹ̀jáde náà sọ wí pé, “ìdínkù nínú àwọn ìdíyelé Form A ti bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí yóò bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 2022”.

Èsì ilé ẹ̀kọ́ giga Manchester Metropolitan Yunifásití

Advertisement

TheCable kàn sí àwọn olúṣàkóso ilé ẹ̀kọ́ gíga Manchester Metropolitan Yunifásiti  láti ṣe ìwádìí àhesọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní ó wá láti ilé ẹ̀kọ́ náà.

“A mòye pé bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò mú Form A kúrò nílẹ̀ ní ìparí ọdún yìí. Nítorínáà a fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ní ìtọ́sọ́nà tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí,” agbẹnusọ ilé ẹ̀kọ́ náà ni ó wí báyìí.

Advertisement

Iamudaju

Osita Nwanisobi, olùdarí ẹ̀ka ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ti bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ wí pé irọ́ gbá ni àtẹ̀jáde tí ó wá láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Manchester Metropolitan Yunifásiti.

Advertisement

Nwanisobi ní,“Ìlànà yìí ò wá láti bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”

Ó rọ àwọn òbí àti akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n má ṣe ṣ’àfiyèsí àtẹ̀jáde náà pé kí wọ́n san ọ̀pọ̀ lára owó ẹ̀kọ́ wọn pẹ̀lú Flywire síwájú  ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá, ọdún 2022.

Advertisement

Àbọ̀ Ìwádìí

Àbájáde ìwádìí fihàn pé bánkì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò tíì ṣe ìkéde ìlànà pé wọn yóò fòpinsí lílo Form A ní ìparí ọdún yìí. Àhesọ ni ọ̀rọ̀ yìí.

 

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.