--Advertisement--
Advertisement

Ǹjẹ́ fífi ọwọ́ ra nkan ọmọkùnrin kí àtọ̀ lé jáde lè jẹ́ kí wọn pá lórí?

Àtẹ̀jáde kan lórí ayélujára gbé ahesọ pé kí ènìyàn máa fi ènìyàn máa fi ọwọ́ ra nkan ọmọkùnrin kí àtọ̀ lè jáde (masturbation) lè fa ìpàdánù irun orí àwọn ọkùnrin.  

Olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter) kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eric-@amerix, fi atẹjade náà sí ojú òpó rẹ pé fífi ọwọ́ ra nkan ọmọkùnrin kí àtọ̀ wọn lé jáde maá ń jẹ kí wọn pá ní orí.

“Ọkan nínú àwọn oun tí máa ń fa ìpàdánù irun orí ni wí pé fífún ara ẹni ní adùn ibalopọ. Dida omi ara/àtọ̀ (oun tí ó máa ń di ọmọ tí ó máa ń jáde láti inú nkan tí àwọn ọkùnrin fi máa ń lopọ pẹ̀lú obìnrin) laibikita màa ń fa kí ènìyàn pàdánù àwọn oun tí ń ṣe ara lóore (nutrients) eléyìí tó máa ń jẹ kí irun hù dáadáa. Tí ẹ bá tún pàdé ọkùnrin tí irun rẹ̀ ń ré jẹ, ẹ fi tó létí pé kí ó se ìtọ́jú àtọ̀ rẹ,” àtẹ̀jáde náà wí báyìí.

Àwọn olùmúlò ti ṣ’atunpin àtẹ̀jáde náà ní ìgbà egbèje, wọn sì bu ọwọ́ ìfẹ́ lú ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún mẹsan dín ní igba.

Lórí ìkànnì ibaraẹnidọrẹ (Facebook), wọn ṣ’atunpin atẹjade yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà lórí oríṣiríṣi ojú òpó. Ìkan nínú wọn ni ẹni tí a mọ sì Emem Nelson tó ṣ’àpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́bí oníṣègùn òyìnbó pẹ̀lú olutẹle ẹgbẹ̀rún mẹsan.

Olùmúlò míràn tí ó ń jẹ́ Jay Ade ṣ’atunpin ahesọ yi sí Medriod Elite City, ojú òpó kan ní orí Facebook t’óní olutẹle ẹgbẹ̀rún mẹsan.

Advertisement

Iṣaridaju

Merriam-Webster Dictionary, ìwé fún itumọ èdè òyìnbó ṣ’apejuwe ibaraẹniṣere gẹ́gẹ́bí fífi ojú ara ẹni ṣeré kí àtọ̀ lè jáde ní ìgbà tí a bá ń ronú ibalopọ, èyí tí máa ń fún ni ní ìtẹ́lọ́rùn ibalopọ.

Èyí túmọ̀ sí pé, ibaraẹniṣere lé jẹ́ afọwọṣe tàbí kí ara kan ara, yàtọ̀ sí ifayaluya, àti kí ènìyàn máa ronú nípa ibalopọ, tàbí akojọpọ àwọn nkan wọ̀nyí.

Ìwé Ìròyìn TheCable kàn sí àwọn amòye nípa iṣẹ́ òògùn òyìnbó láti mọ̀ bóyá imọ sayẹnsi ṣe àtìlẹ́yìn àhesọ wí pé ibaraẹniṣere tàbí dida àtọ̀ laibikita màá n jẹ ki ènìyàn pa l’órí.

Advertisement

Ọjọgbọn Best Ordinioha, tí ó jẹ onímọ̀ nípa ẹ̀ka tó ń ṣe ìtọ́jú ìlera ọpọ ènìyàn láwùjọ, sọ pé irọ́ ni àhesọ yìí, ó fi kún un wí pé kò sí àjọṣepọ̀ kankan nínú irun orí tó ré jẹ tàbí irun orí tí kò hù mọ àti fífi ọwọ ra nkan ọmọkùnrin kí àtọ̀ rẹ lè jáde.

Ó ní, olùmúlò ojú òpó náà fi atẹjade náà sí ìta kí àwọn ènìyàn lè máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti wí pé ó ń wá olutẹle tí ó pọ ni.

Advertisement

“Mo lérò pé ó kàn fẹ́ ṣe àgbàsọ lásán ni. Àmọ́ oun tí ó ṣe yìí lè koba tàbí fà irokiro nípa àwọn ọkùnrin tí irun wọn ti pá jẹ, bí àwọn ènìyàn bá ri wọn, wọn á rò pé oun tí wọn ṣe nìyẹn,” ọjọgbọn náà ló sọ báyìí.

”Nínú ìmọ̀ ìlera, ènìyàn tó bá ní oomonu ọkunrin (testosterone) lọpọlọpọ lè pàdánù irun orí, testosterone jẹ́ èròjà omoonu tó máa ń mú kí ọkùnrin dá pé lára-ní àtọ̀ tí ó dára, èyí tí yóò jẹ́ kí ó lè bá obìnrin ní asepọ tí ó dára.

Advertisement

“Àwọn tó ní èròjà omoonu okunrin lọpọlọpọ lè fẹ́ máa ni ibalopọ ní ọpọ ìgbà. Ṣùgbọ́n, orísirísi nkan ló lè ṣẹlẹ̀ tí nkan ọmọkùnrin fi máa dẹnukọlẹ (má sisẹ bí ó ti yẹ). Wàhálà àṣejù lè jẹ́ kí nkan ọmọkùnrin má ṣe dédé, ibalopọ kò ní ṣí ní ọkàn ẹni náà. Mo lérò pé olumulo ojú òpó yìí sọ aṣọdun lásán ni.”

Oun tó lè fa ìpàdánù irun orí 

Advertisement

Francis Agbaraolorunpo, onímọ̀ nípa ètò ìlera ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Unifasiti ti ìjọba àpapọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó (University of Lagos) sọ pé ọpọlọpọ nkan ló ń ṣokùnfà tàbí fa ìpàdánù irun orí. Ọkan nínú wọn ni àjogúnbá ìdílé ènìyàn, àìlera àti lílo kẹ́míkà. Ṣùgbọ́n kìíse dida àtọ̀ laibikita.

“Ikan nínú òkùnfà (oun tí ó ń fa) pipa lórí ni isoro tí ó wà nínú jiini (genetical problem), èyí tí ó jẹ ìsòro tí a bí mọ ẹlòmíràn-òun tí ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ tí a bí pẹ̀lú ènìyàn,” dókítà ló sọ báyìí.

“Àwọn ẹlòmíràn lè ní alopecia tabi àìsàn jẹrunjẹrun bíi àrùn jẹjẹrẹ (cancer), èyí lé jẹ́ kí wọn pàdánù irun orí. Àwọn obìnrin náà le pàdánù irun orí wọn.

“Tí ẹ bá rí ọkùnrin tí irun rẹ̀ pá, ó ṣeéṣe kí ó jẹ abinimọ-oun tí ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn nígbà tí a bíi, o lè jẹ pé jiini ọ̀ún ò farahàn, ṣùgbọ́n tí jiini yìí bá ṣ’abapade àwọn oun kan, onítọ̀ún á gbé jiini yí yọ.”

Àmọ́, onímọ̀ ìṣegun náà tẹnu mọọ pé ibaraẹniṣere níí ṣe pẹ̀lú ipò ọkàn ènìyàn, kò ní nkankan ṣe pẹ̀lú kí ènìyàn pàdánù irun orí.

Ó fi kún-un wí pé tí ọmọkùnrin bá fojú kéré ara rẹ̀, ó lè máa fi ojú ara rẹ̀ seré kí ó lè ní adùn ibalopọ. Ó ní “èyí lè fa aibimọ.”

“Ọmọkùnrin tó bá ń fún ara rẹ̀ ní adùn ibalopọ tí sii máa ń damira ní gbogbo ìgbà lè ní idakọlẹ tàbí aitetebimọ tó bá di àsìkò ibalopọ pẹ̀lú aya tàbí obìnrin tí ó ń fẹ́.

Àbájáde ìwádìí

Irọ́ ni ahesọ pé fífi ọwọ́ ra nkan ọkùnrin kí àtọ̀ rẹ lè jáde lè fa ìpàdánù irun ori àwọn ọkùnrin. Gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ sayẹnsi, kí ènìyàn máa fi ọwọ ra nkan ọmọkùnrin kí àtọ̀ rẹ̀ lè jáde kii fa kí ènìyàn pàdánù irun orí tàbí pá ní orí.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.