--Advertisement--

Ǹjẹ́ ìwà tó lòdì sí òfin ni kí NNPC máa fún ìjọba ní owó epo rọ̀bì bí Atiku ṣe sọ?

Atiku Abubakar Atiku Abubakar
Former Vice-President Atiku Abubakar.

Abubakar Atiku, igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí sọ pe àṣẹ tí ìjọba àpapọ̀ pa fún Nigerian National Petroleum Company Limited (NNPCL), ẹ̀ka ìjọba tí ó ń ṣe àkóso epo rọ̀bì pé kí wọ́n máa fi owó tí wọ́n bá pa/rí ní orí epo sí àpò Central Bank of Nigeria (CBN), Banki ìjọba àpapọ̀, lòdì sí òfin.

Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́hìn ìgbà tí Olayemi Cardoso, gómìnà CBN sọ pé banki tí ó ga jù lọ náà ń dawọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka ìjọba tí ó ń ṣètò owó nínọ́ àti NNPC láti lè jẹ́ kí “gbogbo àwọn owó tí ó wọlé fún Nàìjíríà láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn padà sí àpò banki ìjọba àpapọ̀.”

Nígbà tí ó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ gómìnà CBN náà, igbákejì Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí náà, ẹni tí ó jẹ́ olùdíje tẹ́lẹ̀rí fún ipò Ààrẹ Nàìjíríà wí pé àmọ̀ràn náà kò ní fún NNPC ní àyè bí òfin ṣe fún un.

“N kò ro aburú nípa pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ jẹ́ kí CBN máa ṣàkóso owó tí NNPCL ń rí. Àmọ́, ó lòdì sí òfin,” Atiku ló sọ báyìí.

Advertisement

“Àṣẹ tí kò bá òfin mu ni.”

Ó sọ fún ìjọba pé kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn ohun tí òfin sọ, kí wọ́n sì jẹ́ kí NNPCL ṣe àkóso àwọn ǹkan bí ó ṣe yẹ.

ÀGBÉYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ

Advertisement

NNPC, tí ó padà di NNPCL, ẹ̀ka ìjọba lè rà tàbí tà (ṣe òwò tàbí káràkátà) ní ìlànà tí òfin tí a mọ̀ sí Petroleum Industry Act (PIA) gbé kalẹ̀.

Nípa ìdí èyí, ẹ̀ka àlákóso epo náà di ẹ̀ka tí ó lè ṣe káràkátà ní ọdún 2021 tí òfin tí a mọ̀ sí Companies and Allied Matters Act (CAMA), sì fi ọwọ́ síi.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi àkójáde NNPCL, Muhammad Buhari, Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí sọ pe ẹ̀ka tí ó ń ṣàkóso epo naa “yóò ní àǹfààní láti ṣe eto wọn ní ọ̀nà tí wọ́n bá ríi pé ó bójú mu àti pé kí wọ́n má kọ ominú nípa àwọn àgbékalẹ̀ ìjọba bíi treasury single account, public procurement and fiscal responsibility act.”

Àmọ́sá, ijọba àpapọ̀ ni ó ni NNPCL pẹ̀lúpẹ̀lú pé ìjọba fẹ́ tà lára àwọn ìpín tàbí àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ ti ẹ̀ka Alákóso èpò náà fún àwọn afowósòwò ní ọjọ́ iwájú.

Advertisement

KÍ NI ÒFIN SỌ?

NNPC, gẹ́gẹ́bí PIA ṣe wí, lè mú ìdá ní ọ̀nà ogún èrè tí wọn bá jẹ dání, wọ́n sì lè fi ìdá ní ọ̀nà ọgọ́rin tí ó kù ṣílẹ̀ fún ìjọba àpapọ̀ nítorí pé àwọn ni òfin fún ní agbára láti ṣàkóso tí ó jú lórí ẹ̀ka náà.

Abala kẹtalelaaadọta (apá keje) PIA sọ pé NNPC tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀yà rẹ̀ lè ṣòwò “láì gba owó lọ́wọ́ tàbí nọ́ owó ìjọba.”

Ní àfikún, ó sọ pé NNPC “gbọ́dọ̀ ṣàkóso ara rẹ̀ bíi ẹ̀ka tí Companies and Allied Matters Act gbé kalẹ̀, wọ́n sì lè sọ iye tí wọ́n bá rí fún àwọn tí wọ́n ní owó nínú owó tí ẹ̀ka náà fii ń ṣòwò. Wọ́n sì lè di ìpín ní ọ̀nà ogún nínú eré wọn mú láti lè rí owó ṣ’òwò.”

Advertisement

Òfin yìí tún sọ pé tí ẹ̀ka náà bá fẹ́ yá ǹkan tàbí gba ìwé-àṣẹ, wọ́n máa san àwọn owó tí ó yẹ kí wón san bíi owó orí, owó àyè lílò, owó ẹ̀tọ́ àti èrè.

Òfin náà tún sọ pé ẹ̀ka náà ni ó jẹ́ Alákóso àdéhùn eto epo, èrè àti àwọn ohun tí ó jọ mọ́ọ fún ìjọba àpapọ̀.

Advertisement

Abala kẹrinlelọgọta (apá kẹta) PIA sọ pé ó pọndandan fún NNPC láti wa àti ta epo lábẹ́ àdéhùn fún iye kan tí ó jẹ́ àjọmọ̀.

Lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n bá ti yọ owó tí wọn ń nọ́ láti ṣe epo, ẹ̀ka náà àti àwọn alájọṣepọ̀ wọn lè pín èrè.

Advertisement

Nínú gbogbo èrè tí ẹ̀ka náà rí, wọ́n ní agbára láti fi ìdá ní ọ̀na ọgbọ̀n wá epo.

Lẹ́hìn tí wọ́n bá ti yọ ìdá yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ lérè tó kù. Wọ́n lè san owó yìí sí àpò CBN tàbí àpò àwọn tí wọ́n bá n ṣòwò owó tí àwọn àti ìjọba bá jọ gbà láti fi sí.

Advertisement

KÍ NI ÀWỌN ONÍMỌ ÌJÌNLẸ̀ WÍ?

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà, Oyeyemi Òkè, amòfin tí ó ń ṣiṣẹ́ ní AO2LAW sọ pé ẹ̀ka náà jẹ́ ilé-iṣẹ́ tí ó ní àǹfààní láti ṣe bisinẹẹsi (ówò/káràkátà) dé àyè kan láì sí ìdíwọ́.

“Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé NNPC kìí se fún gbogbo ènìyàn tí a bá wo òfin tí CAMA gbé kalẹ̀. Ẹ̀ka ijoba fún eto owó níńọ́ tí a mọ̀ sí Ministry of Finance Incorporated (MOFI) àti Ministry of Petroleum Incorporated (MOPI) ni wọ́n ní NNPC. Àwọn ẹ̀ka yìí sì jẹ́ tí ìjọba,” báyìí ni amòfin yìí wí.

“Tí a bá fi ojú àládáni wòó, tí ilé-iṣẹ́ kan bá jẹ́ ti àládáni, àwọn tí wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti sọ bí wọ́n ṣe máa nọ́ owó tí ó wọlé ni àwọn tí ó ní owó tí ilé-iṣẹ́ náà fi ń ṣòwò (MOFI àti MOPI). Tí àwọn méjì yìí bá sọ pé owó NNPC gbọ́dọ̀ lọ sí àpo CBN, n kò rò pé eléyìí lòdì sí òfin ilé-iṣẹ́.”

Lẹ́hìn ìpàdé kan ní Abuja, ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejì, ọdún 2024, NNPC àti CBN sọ pé àwọn ti “ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ pé kí NNPCL fi owó tí ó jọ jú nínú eré wọn pamọ́ sí ọwọ́ CBN.”

Ninu atẹjade kan, àwọn ẹ̀ka méjèèjì jọ sọ pé àwọn tí ń darí bí NNPC yóò ṣe máa nọ́ owó rẹ̀. Wọ́n fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé eléyìí kò túmọ̀ sí pé NNPC máa dá àjọṣepọ̀ tí ó wà láàárín àwọn àti àwọn banki gbogbo ènìyàn dúró.

Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì, ọdún 2024 Cardoso fi tó àwọn ènìyàn létí pé, lẹ́hìn NNPC, àwọn ẹ̀ka ìjọba mìíràn mọ̀ nípa owó tí NNPC gbọ́dọ̀ fi pamọ́ sí ọ̀dọ CBN.”

Àwọn ẹ̀ka yìí àti àwọn mìíràn máa ń fi owó tí wọ́n bá rí ránsẹ́ sí àpo ìjọba àpapọ̀.

Owó yìí (monthly federal allocation) ni federation account allocation committee (FAAC) máa ń pín ní osoosù (monthly) fún àwọn ẹ̀ka ìjọba mẹtẹẹta- ijoba àpapọ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ (federal, state and local governments).

“Tí a bá wòó, ń ṣe ni ó yẹ kí ère epo lọ sí àpo ìjọba àpapọ̀. Ìbéèrè tí ó yẹ kí a bi àwọn ènìyàn ni pé níbo ni àpò ìjọba àpapọ̀ náà wà? ṣé àpò àwọn banki aladani ni ó wà àbí àpò CBN? Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, CBN ló gbọ́dọ̀ máa tọ́jú owó tí ó bá ń wọlé fún ìjọba àpapọ̀,” bayìí ni Oke wí.

Tí ètò báyìí bá wà, ó ní pé, kò ní sí àríyànjiyàn láàárin CBN àti NNPC lórí kí wọ́n fi owó sí àpò banki tí ó ga jù náà nítorí pé “ọ̀dọ̀ CBN ni owó ìjọba àpapọ̀ gbọ́dọ̀ wà.”

Jide Pratt, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ epo rọ̀bì àti gaasi sọ pé ìgbésẹ̀ CBN kò lòdì sí òfin. Ó ni pé bíótilẹ̀jẹ́pé NNPC ti di ti aládáni, ìjọba àpapọ̀ ni ó sì níí.

Nípa ìdí èyí, ó ní pé òfin tí ìjọba fi ń darí Nigerian Upstream Petroleum Regulatory Company (NUPRC) náà ni wọ́n fi máa darí NNPC àti èpò rọ̀bì wíwà àti fífọ́.

“Mo gbàgbọ́ pé, ìjọba ti ṣe dáadáa pẹ̀lú àwọn òfin epo rọ̀bì ṣíṣe àti àwọn ǹkan tí NNPC ní láti ṣe.

Ayodele Oni, ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ ní ibi tí a mọ̀ si Bloomfield LP, sọ pé àdéhùn tí ó wà láàárín CBN àti NNPC wáyé kí wọ́n má baà ṣe owó mọ́kumọ̀ku.

Biotilẹjẹpe àdéhùn yìí yé wa, eléyìí kò yanjú wàhálà tí a ní lórí àwọn owó òkè òkun tí à ń ńọ́ ní Nàìjíríà.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé gómìnà CBN “ti sọ̀rọ̀ nípa káràkátà tí ó ti kún ilẹ̀ ní ọ̀nà tí kò yẹ.

Nínú oṣù Kejìlá, ọdún 2023, Mele Kyari, ìkan nínú àwọn ọ̀gá tí ó ń darí NNPC sọ pé NNPC san triliọnu mẹ́rin àti ẹẹdẹgbẹta biliọnu náírà sí àpò ìjọba àpapọ̀. Owó yìí jẹ́ ti oṣù kìíní sí oṣù Kejìlá, ọdún 2023.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní Atiku sọ yìí kìí se òótọ́. Ìjọba ni ó ní owó tí ó jù nínú owó tí NNPC fi ń ṣe owó.

Ìdí rèé tí wọ́n fi ní ẹ̀tọ́ láti gba ìdá ọgọ́rin nínú èrè tí NNPC bá rí.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.