--Advertisement--
Advertisement

Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni pé wọ́n ti mú Naira Marley àti Sam Larry?

NDLEA: Why we chose Naira Marley for campaign against drug abuse NDLEA: Why we chose Naira Marley for campaign against drug abuse
NDLEA: Why we chose Naira Marley for campaign against drug abuse

Atẹjade kan tí àwọn ènìyàn ń pín kiri lórí àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise ti sọ pé àwọn Ọlọpa ti mú Naira Marley, gbajúmọ̀ olórin àti Samson Balógun, agborinlarugẹ tí a fi bẹẹ mọ̀ sí Sam Larry lẹ́hìn ikú Mohbad, olórin gbajúgbajà.

“Ọwọ ti tẹ Naira Marley àti Sam Larry!! Wọn yóò sọ tẹnu wọn nípa ifiyajẹ tí wọ́n fi jẹ Mohbad,” báyìí ni atẹjade láti ọwọ @Mrklassiq_ ṣe wí.

Àwọn ènìyàn tí rí ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀nà mílíọ̀nù mẹ́ta àti ọọdunrun ẹgbẹ̀rún, wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ni ọna ọgbọn ó lé ní irinwo, wọ́n sì pín in ní ọna ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀ta ó lé ní méjìlélógún ní orí ibaraẹnise ẹlẹyẹ tí a mọ̀ sí X (tí a mọ̀ ṣí twitter tẹ́lẹ̀).

Advertisement

Lẹ́hìn X, a tún rí ọ̀rọ̀ tí ó jọ ọ̀rọ̀ yìí lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ níbi tí wọ́n ti sọ pé àwọn Ọlọpa ti mú Naira Marley àti Sam Larry.

Mohbad jẹ olórin tí Marlian Records ń gbé orin rẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀rí. Naira Marley ni ó ni Marlian Records.

Advertisement

Mohbad ní ọjọ́ Kejìlá, ọdún 2023. Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlọgbọn. Wọ́n sì sin ní ọjọ́ kejì.

Ikú rẹ̀ rú àwọn ènìyàn lójú. Ó sì ti fà àríyànjiyàn lórí àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise (social media) àti láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí kò sí ní orí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise.

ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹwàá, ọdún 2022, Mohbad pariwo lórí ibaraẹnise ẹlẹyẹ lórí nkan ti ó pè ní “ipalara” láti ọwọ Marlian Records.

Advertisement

“Nítorí pé mo fẹ́ paarọ ẹni tí ó ń ṣàkóso orin mi, wo ohun tí wọ́n ṣe fún mi ní ilé Marlian,” Ó tẹ ọrọ àwòrán tí ó ti fi ara pá jáde.

O sì tọrọ iranlọwọ nínú ọ̀rọ̀ yìí. Ó sì ní, “mò ń kú sára.”

Àwọn ènìyàn sọ pé awọn eniyan Marlian Record dẹrubaa léraléra, wọ́n sì ṣe ìpalára fún un ní àìmọye ìgbà títí di ìgbà tí ó fi kú.

Pẹtisọn (petition) kan tí ó dé ọwọ àwọn Ọlọpa ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù kẹfà, ọdún 2023, ni a ti rí ní orí ayélujára. Nínú pẹtisọn yìí, Mohbad sọ ọ̀rọ̀ pé Sam Larry pa òhun lára, ó ba nkan òhun jẹ́, ó sì ń fi ajulọ han òhun. Ó fi pẹtisọn yìí ránṣẹ́ sí Force Criminal Investigation Department (FCID) Annex, tí ó wà ní Alagbọn ní ìlú Èkó (Lagos).

Advertisement

Sam Larry kò lo ohun ìgbàlódé ibi tí àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán ara wọn mọ́ nítorí ọ̀rọ̀ kobakungbe tí àwọn ènìyàn sọ síi nítorí pé wọ́n rò pé ohun ló ṣe ìpalára fún Mohbad, Naira Marley tí bẹ̀rẹ̀ sí ní pàdánù àwọn ènìyàn tí ó n tẹlee lórí àwọn ohun ìgbàlódé ibaraẹnise nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

ÀWỌN AGBOFINRO KÒ TÍÌ MÚ NAIRA MARLEY ÀTI SAM LARRY

Advertisement

Àyẹ̀wò tí TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe fi yé wa pé àwọn Ọlọpa kò tíì mú Naira Marley àti Sam Larry láti fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹnu wò nípa ikú Mohbad.

“Irọ́ ni ìròyìn yìí. Wọn kò tíì mú ẹni kankan,” Oluniyi Ogundeji, agbẹnusọ fún FCID ní ìlú Èkó ló sọ bayii.

Advertisement

TheCable ti ṣe atẹjade pé àwọn Ọlọpa ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ikú akọrin náà.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2023, àwọn ènìyàn mẹ́tàlá tí a kó jọ láti lè ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà sọ pé wọn máa òkú rẹ̀ láti lè mọ irú ikú tí ó paa.

Advertisement

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Ọ̀rọ̀ tí ènìyàn kan sọ pé àwọn Ọlọpa ti mú Naira Marley àti Sam Larry kìí se òótọ́.

Ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́. Wọn kò tíì mú ẹni kankan.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.