Àwòrán kan tí àwọn ènìyàn ti pín ní àìmọye ìgbà lórí àwọn ohun ìbáraẹnise ìgbàlódé (social media) ti sọ pé Bello Matawalle, gómìnà Ìpínlẹ̀ Zamfara tẹ́lẹ̀rí gbẹ́ ilẹ̀ tí ó sì kó àwọn ọkọ̀ olówó ńlá sì inú rẹ̀.
Gẹ́gẹ́bí àkòrí àwòrán yìí ṣe wí, tuntun ni àwọn ọkọ̀ náà. Matawalle ti di minisita fún ètò ààbò lẹ́hìn ìgbà tí ó ṣe gómìnà.
“Nkan ṣe! ẹ sunkún fún àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè wa!”, báyìí ni àkòrí náà ṣe wí.
“Àwọn ọkọ̀ tuntun ni Matawalle, gómìnà Ìpínlẹ̀ Zamfara rà tí ó sì kó sí abẹ́ ilẹ̀. Kí ló dé tí àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú ṣe burú báyìí?”
Advertisement
Àwòrán yìí ṣe àfihàn àwọn ọkọ̀ ìgbàlódé olówó ńlá-ńlá tí àwọn ènìyàn kó sí inú ilẹ̀ tí wọ́n kó iyẹpẹ rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan.
Àwòrán náà tí àwọn ènìyàn pín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní orí wasapu (WhatsApp), tí wọ́n sì tún pín ní orí ohun ìbáraẹnise alami krọọsi (X, formerly called Twitter) jẹ́ ti VANPDP, àwọn ẹgbẹ́ kan tí wọn máa ń ṣe àtilẹyin fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP).
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ orí ohun ìbáraẹnise alámì krọọsi náà ṣe wí, àwọn ìjọba rí àwọn ọkọ̀ náà, wọ́n sì gbà wọ́n lọ́wọ́ Matawalle, ẹni tí ó ti di minisita nísìnyí.
Advertisement
Láti ìgbà tí àwọn ènìyàn tí fi ọ̀rọ̀ náà síta ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2023, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà aadọsan ni ó ti wòó. Àwọn ènìyàn mejidinlẹgbẹta ló fẹ́ràn rẹ̀. Àwọn ènìyàn irinwo àti méjìdínlọgbọn ló pín in, àwọn ènìyàn irínwó o dín ni mẹrindinlọgbọn ló fẹ́ràn rẹ̀.
Ó yẹ kí ó fi ojú ba ilé ẹjọ fún ìwà olè jíjà, báyìí ni ọ̀rọ̀ tí Emmanuel Enoidem, agbẹjọro tí ó sì tún jẹ́ agbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ òfin fún PDP ṣe wí.
Àwọn ènìyàn kan tí a mọ̀ sí awakeningafrica1 tún pín ọ̀rọ̀ yìí lórí TikTok, èyí tí ó jẹ́ ibi ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín ohun ti ó máa ń mú àwọn ènìyàn laraya tàbí mú inú wọn dùn.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin ati mọ́kànlá ni ó wòó. Ẹgbẹ̀rún méjìlá àti igba ló fẹ́ràn rẹ̀. Àwọn ènìyàn ẹẹdẹgbẹrìn àti ookandinlogoji ló fi pamọ. Àwọn ènìyàn irínwó àti àádọ́rin ó dín ìkan ló sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn ènìyàn ọọdunrun ó lé ní aadọta àti mẹ́ta lo pín in.
Advertisement
Njẹ́ òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí?
Discovered and sized from Ex-Gov of Zamfara state, your current Minister of State for Defence. pic.twitter.com/o4ckB0vDi4
— VANPDP (@VANPDPNg) December 14, 2023
Advertisement
AGBEYẸWO
Nígbà tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yii, a ríi pé wọ́n ti pín ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹhin kí àwọn ènìyàn tó máa ṣe atunpin rẹ̀ lórí àwọn ohun ìbáraẹnise ìgbàlódé (social media) ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Advertisement
“Wo nkan ti àwọn ọmọ ológun IEA rí ní agbègbè Balkh,” olumulo ohun ìbáraẹnise alami krọọsi ni ó sọ báyìí ní ọjọ́ kẹtalelogun, oṣù kọkànlá.
Balkh jẹ́ agbègbè kan ní orílẹ̀-èdè Afghanistan. Àwọn afipasenkan tí a mọ̀ sí Taliban gba agbègbè náà padà ní ọdún 2021, wọ́n sì pèé ní Islamic Emirate of Afghanistan (IEA).
Advertisement
Atẹjade miran láti ọwọ́ Reddit sọ pé àwọn oloselu jẹgudujẹra ní Afghanistan ló bo àwọn ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ kúrò ní Afghanistan.
Atẹjade kan ní orí ayélujára sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan tí àwọn ènìyàn fi síta ní ọjọ́ kẹrin, oṣù Kejìlá.
Advertisement
Ọ̀rọ̀ yìí sọ pé lẹ́hìn ìgbà tí Matawalle kùnà láti ṣe gómìnà Zamfara ní ẹ̀ẹ̀kejì, wọ́n ní ó kó àwọn ọkọ̀ tí ó ju àádọ́ta lọ nígbà tí ó fẹ́ gbé ìjọba sílẹ̀.
Dauda Lawal, ẹni tí ó di gómìnà Ìpínlẹ̀ Zamfara lẹhin ìgbà tí Matawalle gbé ìjọba sílẹ̀ fi ẹ̀sùn kan Matawalle pé àwọn ọkọ̀ ìjọba wà ní ọwọ́ rẹ̀.
Àmọ́sá, kò sì atẹjade tí ó jẹ́ òótọ́ tí ó sọ pé wọ́n bo àwọn ọkọ̀ mọ́lẹ̀ níbì kan ní Nàìjíríà.
Kò sì sí atẹjade kan tí ó jẹ́ òótọ́ tí ó sọ pé àwọn ènìyàn tàbí ẹni kan bo àwọn ọkọ̀ kan mọ́lẹ̀ ní ibì kan ní Afghanistan.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Kò sí aridaju kan tí ó sọ pé Matawalle lọ bo àwọn ọkọ̀ kan mọ́lẹ̀ ní ibì kan.
Add a comment