Ọ̀pọ̀lọpọ̀ atẹjade lórí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise (social media) ti sọ pé mímu omi ilá máa ń jẹ́ kí àwọn obìnrin bí ọmọ ní ìrọ̀rùn.
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe wí, omi yìí jẹ́ omi ilá tí a rẹ̀ sí wẹ́wẹ́, tí wọ́n rẹ sínú omi.
Ilá, èyí tí a mọ̀ sí ẹ̀fọ́ tí ó sì máa ń yọ tàbí fà, jẹ́ ohun tí àìmọye ènìyàn máa ń jẹ ní Afíríkà (ilẹ̀ Aláwọ̀ dúdú), pàápàá jù lọ ní ìwọ̀ oòrùn àti àáríngbungbun àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà.
Lẹ́hìn pé àwọn ènìyàn máa ń jẹẹ́, àwọn olumulo orí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise kan sọ pé àwọn obìnrin lè lòó tí wọ́n bá ń wá ọmọ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ bí ọmọ ní ìrọ̀rùn.
Advertisement
Nínú fídíò kan lórí ohun ìbáraẹnise fesibuuku (Facebook), obìnrin olóyún kan ṣe àfihàn bí ó ṣe ṣe ètò ilá láti lè bímọ ní ẹ̀rọ̀.
Nínú fídíò náà, obìnrin yìí gé ilá sínú nkan, ó sì fi nkan oníke yìi, ó sì ní kí àwọn ènìyàn fi sínú firiji (ohun amunkantutu) fún wákàtí mẹ́rìnlélógún.
Lẹ́hìn èyí, ó ro omi rẹ̀, ó sì fi èso síi kí ó lè dùn.
Advertisement
“Ẹ̀yin obìnrin, mo rí eléyìí níbi kan…Wọ́n sọ fún mi pé ó máa ń ran àwọn obìnrin tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti lóyún lọ́wọ́ láti yé ẹyin (ovulation) tí wọ́n bá muú,” báyìí ni obìnrin yìí ṣe wí.
“Mo bẹ yín, ẹ lòó,” báyìí ni atẹjade orí fesibuuku mìíràn sọ.
Nígbà tí ó ń dá sí ọ̀rọ̀ yìí, olumulo fesibuuku kan sọ pé: “Òótọ́ ni pé ó máa ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yé ẹyin. Ó dára fún obìnrin tí ó bá ń gbìyànjú láti lóyún.
Ẹni tí ó ṣọ̀rọ̀ yìí tún sọ pé ó máa ń jẹ́ kí ẹyin pọ̀ síi. Ó fikùn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó dáa kí ènìyàn lòó ní àràárọ̀ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí nkan oṣù obìnrin bá dáwọ́ dúró.
Advertisement
Àwọn ènìyàn ẹẹdẹgbẹrun àti mẹrinlelogoji ló wo fídíò yìí, àwọn ènìyàn mọkandinlọgọta ni ó fẹ́ràn rẹ̀. Ìdáhùn mẹsan-an ni ọ̀rọ̀ náà ní.
Atẹjade kejì tí wọ́n fi síta ní ibi àwùjọ ìbáraẹnise kan ní àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà irínwó lé ní mẹtadinlọgbọn.
Àwọn ènìyàn dáhùn sí ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀nà irínwó ó lé ní mọkandinlogun. Wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀ ní ọ̀nà irínwó àti mọ́kànlá. Wọ́n pín-in ní ọ̀nà mẹsan-an.
ẸYIN TÍ ÀWỌN OBÌNRIN MÁA Ń YÍN ÀTI OYÚN
Advertisement
Ẹyin yíyín máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹyin tí ó bá ti gbó bá ti ojú abẹ́ obìnrin jáde nígbà tí ó bá ń ṣe nkan oṣù.
Ẹyin yìí yóò lọ sí ibi tí àwọn oloyinbo ń pè ní fallopian tubes. Inú obìnrin yóò sì ṣètò bí ó ṣe máa di nkan tí ó máa di ọmọ.
Advertisement
Oyún máa ń wáyé nígbà tí nkan ọmọkùnrin (sperm) bá dà pọ̀ mọ̀ ẹyin obìnrin.
Tí àwọn obìnrin bá ti lóyún, wọ́n gbọ́dọ̀ máa lo àwọn àwọn ohun asaralóore bíi proteni (protein), iron, folic acid, iodine àti choline ni èdè sayẹnsi àti èdè òyìnbó.
Advertisement
Ó tún ṣe kókó kí wọ́n máa lo àwọn ohun asaralóore mìíràn tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń pè ní calcium, vitamin D, potassium àti fibre.
ÀGBÉYẸ̀WÒ (ÌWÁDÌÍ) Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
Advertisement
Láti lè mọ àwọn ohun tí ó wà nínú ilá, TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára fi ọ̀rọ̀ wá Elizabeth Kembe lẹ́nu wò. Ẹni yìí jẹ́ profẹsọ, ọ̀jọ̀gbọ́n tí ó mọ̀ nípa home economics, ní College of Food Science and Human Ecology, ní University of Agriculture (Unifasiti fún ètò/iṣẹ́ ọ̀gbìn/àgbẹ̀), ní Makurdi, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Benue.
Ó sọ pé oúnjẹ tí a mọ̀ sí ẹ̀fọ́ (ilá) yìí jẹ́ ohun asaraníàǹfààní tí ó ní àwọn ǹkan amáraṣedéédéé tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń pè ní minerals, vitamins àti antioxidants.
Àmọ́, ó ní pé kò sí àrídájú tí ó sọ pé ilá ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ (sex) láàárín ọkùnrin àti obìnrin.
“Àwọn ǹkan tí wọ́n jẹ́ ẹ̀fọ́ tàbí tí àwọn Yorùbá ń pè ní ewébẹ̀ ní ipa kan tí wọ́n máa ń kó. Àwọn kan dáa fún àwọ̀ ara. Àwọn kan máa ń jẹ́ kí ènìyàn sún dáadáa. Àwọn kan sì máa ńjẹ́ kí oúnjẹ rìn kiri níbi tí ó yẹ lára. Èmi kò tíìì rí ẹ̀kọ́ nípa sáyẹ́ǹsì tí ó sọ báyìí,” báyìí ni ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ṣe wí.
“A mọ̀ pé ohun asaralóore ni. Ìlera tí ó wà lára ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ilá,” onímọ̀ yìí ló sọ báyìí.
Ìwádìí kan tí United States National Library of Medicine tẹ̀ jáde fihàn pé ilá dára fún ara nítorí pé ó ní àwọn ohun asáraníàǹfààní tí a mọ̀ sí fibres, carbohydrates, proteins àti minerals ní èdè òyìnbó.
Ìwádìí yìí sọ pé ilá máa ń dènà àìsàn ìtọ̀ sugar. Èyí túmọ̀ sí pé ó ní ipa gidi tí ó ń kó nínú ètò ìlera.
TheCable tún fi ọ̀rọ̀ wá Mohammed Bukar, profẹsọ, onímọ̀ nípa ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ fún àwọn obìnrin tí wọ́n bá fẹ́ bí ọmọ lẹ́nu wò, ní College of Medical Sciences, University of Maiduguri, ní ìpínlẹ̀ Bọrọnu (Borno). Ó sọ pé irọ́ gbáà ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé ilá máa ń jẹ́ kí àwọn obìnrin bí ọmọ ní ìrọ̀rùn tàbí kí oyún níní wọn yá.
“Àwọn ọ̀nà wà láti ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ yìí, gẹ́gẹ́bí òye mi kìí se ohun tí àwọn ènìyàn ti ṣe ìwádìí rẹ̀ ní ibì kan,” onímọ̀ yìí ló sọ báyìí.
“Nígbà tí ìwádìí ṣáyẹ́ǹsi tí ó dájú bá wà nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ẹnì kan lè sọ irú ọ̀rọ̀ báyìí.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Irọ́ lásán-làsàn ni ọ̀rọ̀ yìí. Kò sí ìwádìí ṣáyẹ́ǹsì tí ó sọ pé òótọ́ ni.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gba àwọn obìnrin tí wọ́n nílò ìtọ́jú fún aláboyún ní àmọ̀ràn pé kí wọ́n rí dọ́kítà tí ó mọ̀ nípa àwọn ẹ̀yà ara tí a fi ń bí ọmọ tí àwọn olóyìnbó ń pè ní gynaecologist.
Add a comment