--Advertisement--
Advertisement

Ǹjẹ́ Yahaya Bello ṣe ìpàdé pẹ̀lú Tinubu àti àwọn gómìnà?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ atẹjade lórí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise (social media) ti sọ pé Yahaya Bello, gómìnà Ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀rí, ní ọjọ́ àlàmísì, ṣe ìpàdé pàjáwìrì pẹ̀lú Ààrẹ Bola Tinubu àti àwọn gómìnà pẹ̀lú àwọn minisita kan ní Abuja.

Níbi ìpàdé náà, Tinubu àti àwọn gómìnà náà gbà pé ó yẹ kí ìjọba gba àwọn ènìyàn púpọ̀ sí iṣẹ́ ọlọ́pàá láti lè dín aisifọkanbalẹ kù.

Lẹ́hìn ìpàdé yìí, olumulo ohun ìbáraẹnise alámì krọọsi (X) (tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀rí) fi fídíò tí Yahaya Bello wà nínú rẹ̀ sita níbi tí ó ti dúró pẹ̀lú àwọn gómìnà àti Tinubu ní ibùjókòó isejọba tí a mọ̀ sí presidential villa ní Abuja.

“Yahaya Bello sì ń lọ sí ìpàdé FEC Gẹ́gẹ́bí gómìnà Ìpínlẹ̀ Kogi lẹ́hìn tí ó gbé ìjọba fún ẹlòmíràn,” báyìí ni atẹjade náà ṣe wí.

Advertisement

Àwọn olumulo X mìíràn sọ pé Bello sìí ń ṣe àwọn ìpàdé pẹ̀lú Ààrẹ àti àwọn tí wọ́n ń ṣe gómìnà lọ́wọ́lọ́wọ́ pẹ̀lúpẹ̀lú pé ó ti gbé ìjọba ṣílẹ̀ ní oṣù kìíní, ọdún 2024.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ áwon ènìyàn ni wọ́n rí ọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n sì pín ín, tí wọ́n sì dáhùn síi.

Advertisement

Advertisement

Nínú àwòrán yìí, Bello wà láàárín Hope Uzodinma, gómìnà Ìpínlẹ̀ Imo àti Babajide Sanwo-Olu, gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Tinubu sì wá láàárín gbogbo àwọn gómìnà tí wọ́n wá sí ibi ìpàdé náà.

Ǹjẹ́ Bello lọ sí ìpàdé yìí?

ÀGBÉYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Bello jẹ gómìnà Ìpínlẹ̀ Kogi ní abẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) láti ọdún 2016 sí ọdún 2024. Usman Ododo ni ó gbé ìjọba fún. Wọ́n búra fún ẹni tí ó gbé ìjọba fún yìí ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn, oṣù kìíní, ọdún 2024.

Gẹ́gẹ́bí gómìnà tẹ́lẹ̀, Bello kò ní ẹ̀tọ́ láti s’ojú Ìpínlẹ̀ Kogi níbi ìpàdé pẹ̀lú Tinubu àti àwọn gómìnà. Ododo tàbí igbákejì rẹ̀ ló lè ṣe èyí.

Àyẹ̀wò tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe fihàn pé àwọn ìjọba àpapọ̀ ló pín àwòrán yìí lórí X. Wọ́n lo àwòrán yìí pẹ̀lú àbájáde ìpàdé náà.

Àyẹ̀wò tí a tún ṣe síwájú fi hàn pé wọ́n ya àwòrán yìí ní ìpàdé àkọ́kọ́ tí Tinubu ṣe pẹ̀lú àwọn gómìnà Ìpínlẹ̀ lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n fi ìbò yàn án Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nàìjíríà. Bello jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Kogi nígbà náà.

TheCable tún ṣe àyẹ̀wò tí a mọ̀ sí Google reverse image search ní èdè òyìnbó. Eléyìí fi yé wa pé àwòrán yìí ti wà níta láti oṣù kẹfà, ọdún 2023.

Nígbà tí a tún ṣe àyẹ̀wò sí iwájú síi, a ríi pé aṣọ tí àwọn tí wọ́n wà nínú àwòrán ìpàdé tí ó ti pẹ́ náà wọ̀ yàtọ̀ sí aṣọ tí wọ́n wọ̀ nínú ìpàdé tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ àlàmísì.

Ìjọba àpapọ̀ tí rọ́pò àwòrán ìpàdé tí ó ti pẹ́ náà pẹ̀lú àwòrán ìpàdé pàjáwìrì tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ àlàmísì.

Òdodo wá sí ìpàdé ọjọ́ àlàmísì náà. Ó pẹ̀lú àwọn tí ó wà nínú àwòrán ìpàdé àlàmísì náà.

A ṢE Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Biotilẹjẹpe àwòrán tí ìjọba àpapọ̀ kọ́kọ́ fi síta ló fa àríyànjiyàn yìí, ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn sọ pé Bello wà níbi ìpàdé tí Tinubu ṣe pẹ̀lú àwọn gómìnà níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ àlàmísì kìí ṣe òótọ́.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.