--Advertisement--
Advertisement

Ṣé Atiku ni olórí àwọn alamojuto ọrọ̀ ajé tí Obasanjo ṣe agbekalẹ rẹ̀?

Atiku Abubakar, igbá-kejì Olusegun Ọbásanjọ́, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbàkanrí sọ wí pé òun ni ó jẹ́ olórí tàbí olùṣàkóso àwọn alamojuto ọrọ̀ ajé nígbà ìjọba Ọbásanjọ́. 

Atiku, ẹni tí ó jẹ Ólùdíje fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ ajé ní ibi ifiọ̀rọ̀jomitoroọ̀rọ̀ nípa ọrọ̀ ajé/karakata (National Economic Summit Group-NESG) ṣe ní ìlú Èkó.

“Gẹ́gẹ́bí olórí alákòóso/alamojuto ètò ọrọ̀ ajé/karakata nígbà tí mo jẹ igbá-kejì, mo wà lára àwọn tí ó se agbekalẹ bí ọrọ̀ ajé yóò ṣe lọ déédéé tí mo sì ṣe àgbàtẹru pé kí àwọn aladani dá sí ọrọ̀ ajé. A sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí,” Atiku ni ó wí báyìí.

“Ó dá mi lójú pé wàá rántí ìgbà tí ọrọ̀ ajé ń lọ déédéé, tí nkan kò gbé owó lórí, tí  iṣẹ́ wà, tí ìṣẹ́ kò pọ̀.

Advertisement

“A san ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbèsè tí a jẹ àwọn orílẹ̀-èdè kan.”

Ọbásanjọ́ ṣe Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1999 sí ọdún 2007.

Ṣé òótọ́/òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Atiku wí?

ÌWÁDÌÍ

Advertisement

Ayẹwo tí ìwé ìròyìn TheCable ṣe fihàn pé Ngozi Okonjo-Iweala, minisita tẹ́lẹ̀rí fún ètò isuna tí ó sì jẹ́ ọga pátápátá fún àjọ àgbáyé fún ọrọ̀ ajé (World Trade Organization-WTO) gangan ni ó jẹ́ Alákòóso àwọn alamojuto ọrọ̀ ajé ní ìgbà tí Ọbásanjọ́ ṣe ìjọba.

Ọbásanjọ́ dá àwọn alamojuto fún ọrọ̀ ajé yìí sílẹ̀ ní ọdún 2003 nígbà tí ó se Ààrẹ lẹẹkeji.

Atẹjade nípa gbèsè Nàìjíríà, tí àjọ ibaraẹnise láàárín àwọn orílẹ̀-èdè adulawọ àti ilẹ̀ òyìnbó (Centre for Africa-Europe Relations) sọ wí pé: “Nígbà tí a dibo yan Ààrẹ Ọbásanjọ́ láti ṣe ìjọba lẹẹkeji ní ọdún 2003, ó yan àwọn alamojuto ọrọ̀ ajé, ó sì fi arábìnrin Ngozi Okonjo-Iweala, ẹni tí ó jẹ́ ọga ní Bánkì fún àgbáyé (World Bank) nígbàkanrí ṣe olórí wọn. Àwọn Alamojuto yìí ṣe akitiyan lọpọlọpọ kí àyípadà rere lè dé bá ètò ìdàgbàsókè.”

Nínú ọ̀rọ̀ tí a fi tonileti tí Okonjo-Iweala sọ nípa ipa tí wọn ṣà kí ọrọ̀ ajé lè lọ déédéé, ó gbà wí pé ní ọdún 2003 lẹ́hìn ìgbà tí Ọbásanjọ́ gbáà láyè láti kó àwọn alamojuto ọrọ̀ ajé jọ, Ààrẹ Ọbásanjọ́ pinnu láti jẹ́ olórí àwọn alamojuto náà, ó sì fi Okonjo-Iweala ṣe adarí.

Advertisement

Àwọn Alamojuto náà jẹ́ ènìyàn méjìlá tí wọn ní ìmọ̀ tí ó yekooro nípa ọrọ̀ ajé, bí a ṣe ń mojuto gbèsè, fífún àwọn aladani láyè láti darí ọrọ̀ ajé, ìlọsíwájú àwọn aladani, ètò ìjọba, ètò igbogunti ìwà ṣíṣe nkan mọkumọku, àyípadà rere fún iṣẹ́ ìjọba àti ètò isuna ni wọn ṣe agbekalẹ rẹ̀ fún ọrọ̀ ajé nígbà tí Ọbásanjọ́ ṣe ìjọba.

Lára àwọn ènìyàn méjìlá tí ó wà nínú àjọ alamojuto náà ni Chukwuma Soludo, ẹni tí ó jẹ ọga pátápátá/Gómìnà Bánkì Àpapọ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí, Nuhu Ribadu, adarí àjọ tí ó ń gbógun ti ṣíṣe nkan ọrọ̀ ajé lọ́nà tí kò yẹ àti ikowojẹ/isowo mọkumọku (Economic and Financial Crimes Commission-EFCC), Nasir el-Rufai, minisita nígbàkanrí fún olú ìlú ilẹ̀ Nàìjíríà tí Ìjọba Àpapọ̀ ń ṣe àkóso rẹ̀ (Federal Capital Territory-FCT), Oby Ezekwesili, minisita nígbàkanrí fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́, Bode Augusto, ọga pátápátá nígbàkanrí ní ọ́fíìsì fún ètò isuna, Ifueko Omoigui, alaga tẹ́lẹ̀rí fún àjọ ìjọba Àpapọ̀ tí ó ń rí sí bí owó ṣe ń wọlé àti àwọn mìíràn.

Advertisement

Gẹ́gẹ́bí olórí àwọn alamojuto ọrọ̀ ajé àti minisita fún ètò isuna, Okonjo-Iweala ni ó darí ifiọrọweọrọ tí Nàìjíríà ṣe pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ lowo ní òkè òkun.

Lẹ́hìn ifiọrọweọrọ yìí, Nàìjíríà àti àwọn tí ó jẹ lowo ṣe ìkéde àdéhùn ìparí láti lè dín gbèsè Nàìjíríà kù. Gbèsè náà tó biliọnu méjìdínlógún dọla lẹ́hìn ìgbà tí Nàìjíríà san biliọnu méjìlá dọla nínú gbèsè náà.

Advertisement

ṢÉ IKAN NÁÀ NI ÀWỌN ALAMOJUTO ỌRỌ̀ AJÉ (ECONOMIC MANAGEMENT TEAM) ÀTI IGBIMỌ ỌRỌ AJÉ (NATIONAL ECONOMIC COUNCIL)?

Rárá. Àwọn àjọ méjèèjì kìí se iṣẹ́ kan/ìkan náà.

Advertisement

Nígbà tí Atiku ṣe igbá-kejì Ààrẹ, òun ni ó jẹ́ adarí igbimọ bí ọrọ̀ ajé yóò ṣe lọ déédéé.

Ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ tí ẹnikan kọ tí ó wà ní orí wẹbusaiti Yar’Adua Foundation sọ wí pé: “Gẹ́gẹ́bí igbá-kejì Ààrẹ, Atiku jẹ alága igbimọ tí ó ń rí sí ọrọ̀ ajé tí ó kó àwọn onímọ̀/olóye tí wọn mú àyípadà rere bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà jọ láàárín ọdún 2000 àti ọdún 2007.”

A dá igbimọ ọrọ̀ ajé yìí sílẹ̀ nípasẹ̀ ìwé òfin tí Ìjọba Àpapọ̀ Nàìjíríà, tí a ti ṣe àtúnṣe rẹ̀ tí ó wà ní apá kẹtalelaaadọjọ, abala Kínní àti ipinrọ kejidinlogun àti ikọkàndínlógún tí apá Kínní, ibi kẹta tí a yà sọtọ.

Bí ìwé òfin ṣe wí, iṣẹ́ igbimọ ọrọ̀ ajé ni láti máa “gba Ààrẹ ní amọran nípa ọrọ̀ ajé àti ní pàápàá jùlọ láti máa ṣe agbekalẹ bí ọrọ̀ ajé yóò ṣe máa lọ déédéé fún gbogbo àwọn ìjọba Nàìjíríà.”

Àwọn tí ó wà nínú igbimọ náà ni igbá-kejì Ààrẹ, ẹni tí ó jẹ alága, àwọn gómìnà mẹrindinlọgbọn ilẹ̀ Nàìjíríà, Gómìnà Bánkì Àpapọ̀ Nàìjíríà àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba mìíràn.

Ẹni tí ó jẹ́ adarí igbimọ ọrọ̀ ajé nísinsìnyí ni Yemi Osinbajo, igbá-kejì Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Igbimọ náà máa ń ṣe ìpàdé lẹẹkan nínú oṣù.

A ṢE Ọ̀RỌ̀ NÁÀ

Ọ̀rọ̀ tí Atiku sọ pé òun ni Olórí àwọn alamojuto ọrọ̀ ajé kìí se òtítọ́. Ọdún 2003 ni wọn dá àwọn alamojuto yìí sílẹ̀ nígbà tí Ọbásanjọ́ ń ṣe ìjọba.

Ààrẹ Ọbásanjọ́ ni alákòóso tí Okonjo-Iweala sì jẹ́ adarí àwọn alamojuto náà.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.