Ní ọjọ́ ketàdínlogun oṣù kẹfà, ìròyìn tàn ràn-ìn lórí ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter pé ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin apapo, Ahmad Lawani kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀.
Àwọn àtẹ̀jáde kan lórí ìkànnì náà wi pe ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party (APC) sílẹ̀, ó sí tí darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alatako, Peoples Democratic Party (PDP).
“Ahmad Lawan ti kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC, o sì ti darapọ̀ mọ́ PDP torí pé o fẹ ṣetọju ibujoko rẹ̀ ni Ile igbimo asofin apapo, kìíṣe pé ó fẹ́ sin awọn ènìyàn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba agbegbe rẹ̀. Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́: àpò arawọn ní wọ́n lé,” báyìí ni èyán kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ Mustapha kọ sí ojú òpó ìkànnì abẹ́yẹfò rẹ.
Advertisement
Àtẹ̀jáde yìí ti ní, ókéré jù, atunpin ní ọnà egbeje le ni ogoji ati mejo, àwọn olumulo oju opo naa ti iye won je egberun ni ona merin ati eedegbeta o le mejo sí tí bù ọwọ ìfẹ́ lu.
Ojú òpó kan tó gbé àmì àṣẹ ìkànnì Twitter, @GoldmyneTV náà gbé àhesọ ọ̀rọ̀ naa pe Lawan ti kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílè. Ojú òpó yìí ní òntẹ̀lẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbò (50,000), ó sí ma ń sàtúpín àwọn ìròyìn nípa eré ìdárayá.
Advertisement
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí
Alága ẹgbẹ́ APC, Abdullahi Adamu ti kọ́kọ́ sọ pé Lawan ni olùdíje àjùmọ̀yàn ẹgbẹ́ náà.
Àbálọ àbábọ̀, Lawan kópa nínú ìdíje náà, tí ó sí gbé ipò kẹrin pẹ̀lú ìbò éjì lé ní àádọ̀jọ.
Advertisement
Ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin náà kùnà níbi ìdìbò abẹ́nú náà, èyí tí Bola Tinubu, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ìpínlè Èkó ti jáwé olubori pẹlu ìbò egbefa ati aadorin o lekan .
Iṣamudaju
Ní àsìkò tí ìròyìn yìí n tán ràn-ìn lórí ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter yìí, àyẹwò TheCable fihàn pé kò sí ilé iṣẹ́ ìròyìn tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé tó gbé ìròyìn náà.
Nínú àtẹ̀jáde kan ní ọjọ́ àbámẹ́ta, Ọlá Awoniyi, agbẹnusọ ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin náà sọ wípé ìròyìn òfégè ní àhesọ naa pe Lawan kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Advertisement
Ṣáájú nínú ọ̀sẹ̀ yìí, ààrẹ ilè ìgbìmọ̀ aṣòfin ti kéde pé àwọn aṣòfin méjì láti ìpínlè Kebbi ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀.
Yahaya Abdullahi, aṣoju s’ofin Kebbi North, ati Adamu Aliero, aṣoju s’ofin Kebbi Central, fi ìwé ranṣẹ pe won ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀, wọ́n sì ti darapọ̀ mọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Advertisement
“Fídíò kan tó ṣàfihàn ibi ti ààrẹ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ń ka lẹ́tà ti Aliero fi rànṣẹ̀ ní àwọn èèyàn kàn ṣe ayédèrú rẹ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn rò pé Lawani ti kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀,” Awoniyi ni o wi bayi.
Ó ṣàlàyé pé ojúlówó fídíò jẹ́ ìsẹ́jú mẹ̀ta, àti ìṣẹ́jú aaya ọgbọ̀n, fihàn pé Lawan ka lẹta Aliero, tí ó fi to àwọn akẹgbẹ́ rẹ leti pe òun ti kúrò lẹgbẹ òṣèlú kan sí omiran. Fídíò yìí ní àwọn kan gé kúrú si ìṣẹ́ju-aaya mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.
Advertisement
Ẹ̀yà fídíò tí wọ́n tí ṣatunkọ rẹ yìí ni wọ́n ti fi tan àwọn ará ìlú.
Advertisement
Àbájáde ìwádì
Àhesọ ọ̀rọ̀ nipe ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ahmad Lawan ti kọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ fún ẹgbẹ́ alatako PDP. Iro gbàá ni èyí.
A kọ ìròyìn yìí ni ajọṣepọ pẹlu Report for the World, eto agbaye ti o ṣe atilẹyin iṣẹ iroyin tiwa-n-tiwa.
Add a comment