Fónrán fídíò kàn tó ṣ’àfihàn Rauf Aregbesola, mínísítà fún ọrọ abẹlé, tó sì jẹ gómìnà Ìpínlẹ Osun tẹlẹrí ní ibi tó ti ń ṣ’àjọyọ, ni àwọn ènìyàn ń pín káàkiri orí ayélujára.
Àwọn olumulo ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter) ti ṣ’atunpin fídíò náà níbi tí wọn ti ṣe àhesọ pé mínísítà náà ń jó/yọ̀, ó sì ń pẹgan Gboyega Oyetola, gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun lẹ́yìn àṣẹ ilé-ẹjọ́ gíga ní ìlú Abuja tó ní Oyetola kò yẹ láti díje du ipò gómìnà ní ìgbà kejì.
Olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ @IfedolapoOsun fi àtẹ̀jáde náà sí ojú òpó rè ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹsàn-án, ọjọ́ tí ilé-ẹjọ́ gíga fagilé iyansipo Oyetola àti igbá-kejì rẹ̀ tí a mọ sí Benedict Alabi.
Àwọn aṣàmúlò ojú òpó ti wo fónrán náà ní ìgba ẹgbèrún mẹtalelogun àti irinwo, wọ́n bu ọwọ́ ìfẹ́ lúù ni ìgba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rún dín ní mókànlá, wọ́n sì ṣ’atunpin rẹ̀ ní ọna ọọdunrun àti mejilelaaadọta.
Advertisement
Aregbesola Today after Court Nullified Gboyega Oyetola's candidacy 🤣🤣 pic.twitter.com/2fEi8tbS1P
— Governor Ifedolapo Osun (@IfedolapoOsun) September 30, 2022
Advertisement
Wọ́n ṣ’atunpin fídíò náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìfòrí yìí: “Aregbesola lónìí, lẹ́yìn tí ilé-ẹjọ́ fagilé iyansipo Gboyega Oyetola.”
Àwòrán Ademola Adeleke, ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ìbò yàn sí ipò Gómìnà ni Ìpínlẹ̀ Ọsun ló wà ní profaili ojú òpó tó ṣ’atunpin fídíò náà, èyí tó si ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùmúlò lọ́nà, tí wọn sì rò pé Adeleke ló pín fídíò náà.
Ìròyìn atẹhinwa
Emeka Nwite ni adajọ tó jókòó lórí ẹjọ́ náà pẹ̀lú nomba: FHC/ABJ/CS/468/2022 tí ẹgbẹ ́òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) sì jẹ́ olupẹjọ.
Advertisement
Nínú igbẹjọ náà, Mai Mala Buni, ẹni tí ó jẹ́ alága ẹgbẹ ́òṣèlú All Progressives Congress (APC) àti àwọn mẹ́rin míràn ni wọ́n jẹ́ olujẹjọ.
Nwite dá ẹjọ́ pé iyansipo Oyetola àti igbá-kejì rẹ̀ lòdì sí òfin nítorípé lábẹ́ òfin, Buni, ẹni tí ó fi orúkọ àwọn Oludije náà ransẹ sí àjọ elétò ìdìbò ní orílẹ̀-èdè Naijiria, Independent National Electoral Commission (INEC) kùnà nínú abala òfin ọgọsan lé ní mẹ́ta àti ìpín kẹta abala eejilelọgọrin, 82 (3) ti òfin ìdìbò (Electoral Act) ti ọdún 2022.
Iṣaridaju
Àyẹwò ìwé ìròyìn TheCable fihàn pé olùmúlò ìtàkùn ibaraẹnidọrẹ (Facebook), Ajiboye Maroof Akinlabi, fi fídíò náà sí ojú òpó rẹ̀ ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣù kẹsàn-án, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìfòrí yìí: ”Minisita ọ̀rọ̀ abẹle, Ogbẹni Rauf Aregbesola ṣ’àjọyọ̀ ọjọ́ ìbí ìyàwó rẹ̀, Ìyáàfin Sherifat Aregbesola, ẹni tí ó pé ọmọ ọdún mejilelọgọta.”
Advertisement
TheCable kàn sí Kikiowo Ileowo, olùrànlọ́wọ́ Rauf Aregbesola, ó ní: “ajọyọ ọ̀ún kò níí ṣe pẹ̀lú ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ lórí iyansipo Oyetola”, ó fi kún-un wí pé wọ́n gbà fídíò náà sílẹ̀ ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ní ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí aya Aregbesola.
Àbájáde ìwádìí
Advertisement
Aṣinilọ́nà ní fídíò tó s’àfihàn Aregbesola ní ibi tí ó ti ń ṣ’àjọyọ̀ ìdájọ́ tó fagile iyansipo Gboyega Oyetola.
Ìgbà àkọ́kọ́ tí fídíò náà dé orí ayélujára ni ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kẹsàn-án, ilé-ẹjọ́ sí jókòó lọ́jọ́ kejidinlọgbọn, oṣù kẹsan.
Advertisement
Add a comment