--Advertisement--
Advertisement

Ṣé òtítọ́ ni wí pé àwọn gómìnà gúúsù ilà-oòrùn ló dá ESN sílẹ̀?

Peter Obi, olùdíje fún ipò ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party), sọ láìpẹ́ yìí pé àpapọ̀ àwọn gómìnà ìhà gúsù ilà-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló da ikọ̀ aláàbò Eastern Security Network (ESN) silẹ.

Olùdíje náà sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kẹẹdogun, oṣù kẹwa, ọdún 2022, ní ibi ìpéjọ ifọrọwerọ ti Arewa Joint Committee ní Ìpínlẹ̀ Kaduna.

Nínú fọ́nrán àpéjọ náà, ènìyàn kan bèrè pé, “kíni ìdí tí àwa ènìyàn àríwá Nàìjíríà ṣe máa gbà ẹ́ gbọ́, nígbà tí ó kò fi ìgbà kankan ṣe ìdálẹbi kónílé-ó-gbélé ọjọ ajé ní gúúsù ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà?

“Kíni ìdí tí àwọn ènìyàn àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe gbọ́dọ̀ fi ọkàn tán ẹ nígbà tí àwọn alága ìpolongo ìbò fún ẹgbẹ́ òsèlú àwọn osisẹ tí o gbé kalẹ fún ìpínlẹ̀ Sokoto àti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ míràn ní àríwá orílẹ̀-èdè wa fún ìdíje ipò Ààrẹ rẹ jẹ́ ọmọ ẹ̀yà igbo?

Advertisement

“Kilode tí àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe máa gbà ẹ́ gbọ́, nígbà tí èmi kò fi ìgbà kankan gbọ kí o da IPOB (Indigenous People of Biafra) ati ESN lẹbi fún gbogbo àwọn àṣemáṣe tí wọ́n ṣe?” arákùnrin kan ló bere ìbéèrè yìí.

Ni idahun sí ìbéèrè náà, Obi sọ wí pé kò sí ọ̀nà bí òun yóò ṣe dá ESN lẹbi fún àwọn nǹkan tí wọn ṣe nítorí wí pé àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ gúúsù ila-oorun ni wọn dáa silẹ.

“Awon ìjọba ìpínlẹ̀ gúúsù ilà-oòrùn ló dá ESN sílẹ̀. Àwọn gómìnà Ìpínlẹ̀ gúúsù ila-oorun ló dá ikọ̀ ààbò náà sílẹ̀, kíló le fàá tí mo ma ṣe dá wọn lẹbi? Mo ti sọ̀rọ̀ nípa kónílé-ó-gbélé ọlọsọọsẹ ní gúúsù ìlà-oòrùn, àwọn ènìyàn sì ti mẹ́nuba orúkọ mi nípa ọ̀rọ̀ náà. Ẹ lọ ṣe ìwádìí òun gbogbo tí mo bá sọ.”

Advertisement

Àmọ́sá, ṣé òtítọ ni ọ̀rọ̀ yìí?

Iṣaridaju

Àyẹ̀wò ìwé ìròyìn TheCable fihàn pé ọgbẹni Nnamdi Kanu, adarí ẹgbẹ́ ajijagbara tí a mọ sí Indigenous People of Biafra (IPOB) ló dá ESN silẹ ní oṣù Kejìlá, ọdún 2020.

Ẹgbẹ́ IPOB ti Kanu dá sílẹ̀ ní ọdún 2012, ti pè fún idasilẹ orílẹ̀-èdè Biafra, ìjọba alàdáni fún àwọn ènìyàn gúúsù ila-oorun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lori àhesọ pé wọn kò ri ànfààní t’óyẹ jẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀.

Advertisement

Ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2020, Kanu kede idasilẹ ikọ̀ akọgun ESN. Ó sọ wí pé a dá ikọ̀ akọgun náà silẹ láti máa dàbobo àwọn ènìyàn gúúsù ilà-oòrùn orílẹ̀-èdè wa láti ọwọ́ àwọn agbesunmọmi àti àwọn ọ̀daràn míràn.

Ṣáájú àsìkò yìí, ìròhìn ti tànká orí ayélujára lóri bí àwọn darandaran Fulani ṣe ń kọlù oko ní gúúsù ilà-oòrùn.

Nínú ìkéde rẹ̀, Kanu fi ikọ̀ akọgun ESN wé ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Amọtẹkun ni iwọ oòrùn gúúsù Nàìjíríà àti Miyetti-Allah ni àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó ní, aiṣedede àwọn gómìnà Ìpínlẹ̀ gúúsù ilà-oòrùn Nàìjíríà nípa ètò ààbò tó dájú fún àwọn ará ìlú ló fàá tí wọ́n fi dá ESN silẹ.

Advertisement

Ní ọdún 2021, àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ gúúsù ilà-oòrùn ṣ’agbekalẹ ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Ebube Agu, “lati gbógun ti ìwà ọ̀daràn ní agbègbè náà.”

Dave Umahi, gómìnà Ìpínlẹ̀ Ebonyi, tó tún jẹ́ alága ẹgbẹ́ àwọn gómìnà gúúsù ìlà-oòrùn sọ pé wọ́n da ìkọ aláàbò náà silẹ torí àìsí-ààbò tí ó ń burú sí ní agbègbè náà.

Advertisement

“Gbogbo wá ti fẹnukò láti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan lórí ètò ààbò nì ilẹ̀ wa. Ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí a gbekalẹ fún gúúsù ilà-oòrùn ni a ń pé ní Ebube Agu. Olú ilé-isẹ ikọ̀ náà yóó wà ní ipinlẹ Enugu, láti ibi tí yóò ti máa darí ètò àbò káàkiri gúúsù ilà-oòrùn orílẹ̀-èdè wa,” Umahi ló sọ báyìí.

Àbájáde ìwádìí

Advertisement

Irọ àti isinilọna ni ọrọ ti Obi sọ nípa idasilẹ ESN. Ẹgbẹ́ ajijagbara IPOB ló dá ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà silẹ kìíse àwọn gómìnà Ìpínlẹ̀ gúúsù ila-oorun/ilẹ Igbo. Adijedupo fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn osisẹ náà gbé idasilẹ IPOB àti ESN fún ara wọn.

Advertisement
Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.