--Advertisement--

Ṣé owó ìwo fíìmù ní sínímà ní Nàìjíríà ni ó wọn jù ní àgbáyé?

Arákùnrin kan tí ó máa ń ṣòwò ní Abuja sọ pé owó Tikẹti tí àwọn ènìyàn fi ń wo fíìmù ní sinima ní Nàìjíríà ni ó wọn jù ní àgbáyé.

Arákùnrin yìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yinka Ade-Aluko, jẹ́ ọ̀gá ilé isẹ ti o ń ṣe àfihàn fíìmù tí a mọ sí Doodle-Film Hub, ní Abuja.

Ó sọ pé àwọn tí wọn ń ṣe àfihàn fíìmù ní Nàìjíríà máa ń fi fíìmù hàn fún àwọn tí ó ní owó, wọn kò sì kà àwọn èwe sí.

Ẹni yìí sọ pé ìwádìí ilé isẹ òhun fihàn pé iye tí àwọn tí wọn ṣe àfihàn fíìmù ní sinima (cinema) ní Nàìjíríà ní owó wọn pọ jù ní àgbáyé, àti wí pé wọn kò ṣe nkan náà nítorí ẹni tí kò rí jẹ.

Advertisement

Àmọ́sá, kò sọ ìgbà tí ó se ìwádìí náà.

Ara àwọn ọ̀rọ̀ yìí wo ló jẹ́ òótọ́?

NI ÀWỌN Ó Ń ṢE NKAN YII MÁA Ń WỌN TO SỌ IYE BÁYÌÍ NI OWÓ TIKẸTI SINIMA YÓÒ JẸ́?

Advertisement

Lára àwọn ohun tí wọn máa ń wò láti lè sọ pé iye báyìí ni owó Tikẹti yóò jẹ́ ni iye owó tí wọn fi gba àwọn ènìyàn wọlé, owó orí tí wọn san fún ìjọba àti ìyè tí wọn  nọ láti pèsè ipapanu bíi guguru fún àwọn tí wọn fẹ wo fíìmù.

Àpapọ̀ owó yìí jẹ àwọn owó tí wọn fi ṣe owó náà. Ara owó tí wọn pa ni wọn ti máa yọ èrè.

Àwọn ilé sinima kan máa ń ńọ owó lórí ọ̀rọ̀ ajé yìí ju àwọn kan lọ. Wọn máa ń ṣe eléyìí láti lè jẹ́ kí àwọn oluwofiimu wọn jẹ ìgbádùn ju àwọn tí ó lọ ilé fíìmù olówó pọọku. Ìdí rèé tí iye tí wọn máa ń gba fún Tikẹti ṣe máa ń pọ.

Àwọn ilé ìwofíìmù kan máa ń jẹ ki àwọn oluwofiimu ra Tikẹti wọn lórí ayélujára tàbí láti orí fóònù wọn. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà mìíràn, wọn máa ń sí àwọn owó kan mọ owó Tikẹti tí àwọn ènìyàn ra yìí lórí ayélujára. Ara owó tí wọn máa ń sí mọ owó Tikẹti ni owó orí. Èyí ló fà á tí owó Tikẹti ṣe máa ń pọ nigbamiran.

Advertisement

Àwọn ilé fíìmù kan máa ń dín owó Tikẹti wọn kù láti lè fa ojú àwọn ènìyàn mọ́ra.

Wọn máa ń ní iye kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àgbàlagbà, àwọn tí wọn máa ń wà sinima ní gbogbo ìgbà, ẹdin owó fún àwọn tí wọn bawa pọ.

Àwọn ilé sinima máa ń fi àyè silẹ fún àwọn tí wọn máa ń wà lọpọlọpọ ìgbà, ipanu nígbà tí fíìmù bá ń lọ lọ́wọ́, jíjẹ àti mímú lórí ìjókòó tàbí ìsinmi níbi tí wọn pèsè fún àwọn oluwofiimu pàtàkì.

OWÓ TIKẸTI FÍÌMÙ ÀGBÁYÉ

Advertisement

Iye tí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ififiimuhan máa ń yàtọ̀ sí ara wọn. Ohun tí ó máa ń ṣokùnfà eléyìí ni ibi tí wọ́n bá ti ṣe àfihàn fíìmù.

Iye tí wọ́n máa gbà lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń gbé ibi tí àwọn ènìyàn tí lajú máa ń pọ jù agbègbè tí àwọn ènìyàn kò lajú.

Advertisement

Owó tí wọn máa ń san fún àwọn osisẹ, owó ibi tí wọ́n ń lò, owó tí wọn fi ń tún nkan ṣe lo máa ń jẹ ki wọn sọ pé àwọn yóò gbà iye báyìí lórí Tikẹti tàbí fíìmù kan.

Àwọn tí wọn ni fíìmù máa ń sọ pé ìgbà báyìí ni àwọn sinima gbọ́dọ̀ ṣe àfihàn fíìmù àwọn. Wọn sì máa ń  tà ẹtọ yìí fún àwọn tí wọ́n máa ń ṣe àfihàn fíìmù. Eléyìí ló tún máa ń jẹ ki owó tí wọn máa gbà lórí Tikẹti kan ṣe rí.

Advertisement

Àwọn nkan mìíràn tí ó máa ń jẹ́ kí owó Tikẹti tó iye tí ó tó ni ìgbà isafihan fíìmù, àwọn ohun ìgbàlódé tí wọn lo àti akitiyan tí àwọn tí ó ń ṣe fíìmù máa ń ṣe láàrín ara wọn láti lè ṣe àṣeyọrí ju ara wọn lọ. Àwọn nkan yìí ló máa ń jẹ ki owó Tikẹti máa ń to iye tí àwọn ilé sinima bá pèé.

Lílọ sókè owó jíjẹ àti mímu àti iye owó tí àwọn ènìyàn bá ní nígbà kan ló máa ń jẹ kí àwọn ile fíìmù kan dín owó Tikẹti kù kí wọn máa bá ṣe owó tí kò lérè àti wí pé kí wọ́n má bá kó igbá wọlé.

Advertisement

Ní àgbáyé, sinima àti fíìmù sise jẹ ohun tí àwọn tí wọn ba fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ajé máa ń ṣe.

Ìdí rèé tí owó Tikẹti láti wo fíìmù tí a mọ sí ‘The Bee Keeper’ tó dọ́là mẹwa ní California, US (Amẹ́ríkà), owó yìí sí jẹ dọ́là mẹrin ní Lekki, ní ìlú Èkó (Lagos).

Àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ní àwọn ènìyàn pupọ ní àǹfààní láti rí owó pupọ lórí Tikẹti.

AYẸWO ÀWỌN WỌN Ń ṢE BISINẸẸSI SINIMA NÀÌJÍRÍÀ

Lára àwọn tí wọn ń ṣe bisinẹẹsi yìí ní Nàìjíríà ni Silverbird, Lighthouse, Ozone, Filmhouse àti Genesis.

Ní Nàìjíríà, eré orí ìtàgé tí wà kí sinima tó dé.

Silverbird Group ni ó kọ́kọ́ dá àwọn ilé sinima silẹ ní àwọn àdúgbò àwọn olówó bíi Victoria Island, Lagos  níbi tí wọn ti ṣí Silverbird Galleria ní ọdún 2004.

Nígbà tí àwọn tí wọn ń ṣe fíìmù ní Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé fíìmù jáde ní Nàìjíríà  ní ọdún 2008/2009, ọkàn àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní sí kúrò ní fíìmù orílẹ̀ èdè mìíràn, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wo fíìmù tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe.

Ní nkan bí ọdún 2010, ohun tí a mọ sí DVDs-Digital Video Disks kò tá mọ. Àwọn tí wọ́n ń ṣe fíìmù ní láti wá ọ̀nà mìíràn láti ta fíìmù wọn.

O lè nọ ogún miliọnu náírà láti fi ṣe fíìmù, kí o sì fi sí orí DVDs, kí ó sì má pa miliọnu márùn-ún náírà padà nítorí pé àwọn ènìyàn kan ma ti ṣe ayédèrú ẹ, báyìí ni.

Allen Onyige, ẹni tí ó ń ya fíìmù ṣe wí. Nígbà  yìí ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ràn sinima ní ọdún 2016.

Netflix, àwọn tí wọn ni ohun ìgbàlódé tí wọn fi ń gbé fíìmù jáde lórí ayélujára dé sí Afíríkà ní ọdún 2016. Ajakalẹ aarun kofiidi (Covid19) ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹrin lẹhin èyí, ó sì dé àwọn ènìyàn mọ́ lè. Eléyìí jẹ ki ọkàn wọn sí kúrò ní sinima. Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní wo fíìmù orí ayélujára lọ ju ti sinima.

Ìdí tí wọn fi fẹ́ràn fíìmù orí ayélujára ni pé wọn lè wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àti orisirisi fíìmù, tí wọ́n jẹ́ ojúlówó tí owó wọn kò ni wọn lára.

Àwọn esi ìwádìí tí a rí láti ọwọ Inside Nollywood fi ye wa pé iye Tikẹti tí wọn ta nílé fíìmù jẹ́ bíi miliọnu méjì àti ìdajì ní ọdún 2015 sí miliọnu márùn-ún àti ìdajì ní ọdún 2018. Eléyìí bẹ̀rẹ̀ sí ní dínkù ní ọdún 2019.

Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dínkù síi nítorí pé ailejade àwọn ènìyàn nígbà kofiidi tí jẹ kí wọn fẹ́ràn wíwo fíìmù lóri ayélujára. Àwọn tí wọ́n ń ṣe àfihàn fíìmù ní sinima kò rí owó bí ti tẹ́lẹ̀ láti ìgbà yìí.

Ní Nàìjíríà, àwọn tí wọn ń ṣe fíìmù àti àwọn tí wọn máa ń ṣe àfihàn rẹ ní sinima máa ń pín èrè orí fíìmù ní ọ̀nà ogójì-ogójì-ogún. Sinima tí ó máa ṣe àfihàn fíìmù yóò mú idà ogójì, ẹni tí ó ni tàbí gbé fíìmù jáde yóò mú idà ogójì. Sinima ni yóò mú idà ogún tí ó kù nítorí pé àwọn ni yóò polówó fíìmù yìí.

Ìlànà ọgọ́ta sí ogójì yìí kì í jẹ kí àwọn tí wọn ni fíìmù rí owó tí wọn fi gbé fíìmù jáde tí wọn ba gbe jáde ní sinima. Ìdí nìyí tí wọn fi máa ń fẹ́ràn kí àwọn ènìyàn wòo lórí ayélujára. Eléyìí ló fà á tí àwọn sinima bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe fíìmù fúnra wọn tàbí fi owó lé owó Tikẹti láti lè rí èrè.

Owó jíjẹ àti mímu àti owó tí wọn fi ń ṣe ọrọ ajé ti lọ sókè. Èyí pẹ̀lú ohun tí ó jẹ kí wọn fi owó lé owó Tikẹti.

“Ọrọ ajé ni a ń ṣe. Lóòótọ́ ni pé owó Tikẹti ti lọ sókè, a lè sọ ìdí rẹ,” báyìí ni Patrick Lee, Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí fún àwọn ẹgbẹ́ tí wọn ń gbé fíìmù jáde ní sinima tí a mọ sí Cinema Exhibitors Association of Nigeria (CEAN) ṣe wí.

“Tí a bá fi owó lé owó Tikẹti, ohun tí ìjọba ṣe ló fà á nítorí pé ó máa ń jẹ kí owó àwọn nkan lọ sókè. Owó oṣù àwọn ènìyàn kò lọ sókè. Ìdí nìyí tí wọn kò fi máa ń rí owó yọ fún àwọn nkan tí ó bá wun wọn láti ṣe.”

ṢE OWÓ TIKẸTI SINIMA NÍ NÀÌJÍRÍÀ LÓ WỌN JÙ NÍ ÀGBÁYÉ?

TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára fi ọ̀rọ̀ wá Yinka Ade-Aluko lẹ́nu wò láti lè mọ òótọ́ nípa ọ̀rọ̀ tí ó sọ. Ṣùgbọ́n, a kò rí bá sọ ọ̀rọ̀.

“Tí o bá wo iye owó oṣù tí ó kéré jù àti iye owó Tikẹti ni Nollywood, Bollywood àti Hollywood àti bí àwọn ènìyàn ṣe pọ ni Nàìjíríà (Nollywood) India (Bollywood), USA-United States of America (Hollywood), wa mọ ìdí tí owó Tikẹti fi lọ sókè,” Yinka Ade-Aluko ló sọ báyìí.

Ó ní pé iye tí àwọn ènìyàn bá ń gbà gẹ́gẹ́bí owó oṣù tàbí iye owó tí wọn máa ń rí ló máa fún wọn ní àǹfààní iye tí wọn lè san fún Tikẹti.

Bí ó ṣe wòó, owó oṣù ìjọba tó kéré jù ní Nàìjíríà tí ó jẹ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgbọ́n náírà, èyí tí ó ju dọ́là méjìdínlógún díẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà tí Silverbird ń gbà fún isafihan fíìmù túmọ̀ sí pé ẹni tí ó bá ń gba ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgbọ́n náírà yóò san ìdá tí ó dín ní ọgbọ́n nínú owó oṣù rẹ lórí fíìmù sinima. Ẹni tí ó bá wà ní Amẹ́ríkà yóò san ìdá kan nínú owó oṣù rẹ láti wo fíìmù.

TheCable ṣe àyẹ̀wò owó Tikẹti ní orílẹ̀ èdè ogún. A wá wòó pẹ̀lú owó oṣù (N30,000) ìjọba tó kéré jù ní Nàìjíríà láti lè mọ bóyá owó Tikẹti ní Nàìjíríà ló wọn jù.

Venezuela, orílẹ̀ èdè tí owó oṣù tí ìjọba ń san tó kéré jù jẹ́ dọ́là mẹrin ó lè owó díẹ̀ ($4), èyí tí ó jẹ́ 130 bolivars ní owó Venezuela ló ń fojú fí iná jù nítorí pé ìdá àádọ́rin àti mẹ́rin iye owó tí wọn ń rí ni wọn fi ń san owó oṣù.

Ọ̀rọ̀ tí Ade-Aluko sọ yìí kò wo iye owó Tikẹti àti iye tí àwọn tó ní sinima fi máa ń pèsè ohun ìgbádùn bíi guguru àti àwọn ohun mìíràn fún àwọn tí wọ́n fẹ́ wo fíìmù.

TheCable tún ṣe àyẹ̀wò síwájú síi. A wo iye owó fíìmù ní Nigeria’s Box Office, láti ọdún 2018 sí ọdún 2024 láti lè mọ iye owó Tikẹti.

A wo iye owó Tikẹti àwọn fíìmù mẹ́ta tí àwọn ènìyàn wo jù nínú àwọn fíìmù márùn-ún tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jù ní àárín ọ̀sẹ̀ kìíní sí ikarun ọdún kọ̀ọ̀kan. A sì wo ti ọdún 2018 láti December nítorí pé àwọn nkan tí a lè fi wòó kò tó.

A wá wo iye owó Tikẹti tí wọn ń rí ní ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú iye àwọn ènìyàn tó wá wo fíìmù láàárín ọ̀sẹ̀ kan.

Eléyìí fi ye wa pé ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọrun náírà ó dín díẹ̀ (N1138) ni owó Tikẹti ní ọdún 2018, èyí tí ó di ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀ta náírà ó dín díẹ̀ ní ọgbọ́n náírà (N2571), èyí tí ó dín díẹ̀ ní dọ́là méjì ($1.54) ni wọn ta Tikẹti ní oṣù kìíní, ọdún 2024.

A fi ojú wòó pé wọn lè ta Tikẹti ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún náírà (N500) ní ọdún 2015.

A ṣe àyẹ̀wò owó Tikẹti nisinyi, àwọn fíìmù tí àwọn ènìyàn wò ju ni ‘A Tribe Called Judah’, tí owó Tikẹti rẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín bíi ọgọ́rùn-ún náírà (N3920), ‘Malaika’ tí owó Tikẹti rẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ní ẹgbẹ̀ta àti díẹ̀ náírà (N3670) àti ‘Aquaman: The Lost Kingdom’ tí owó Tikẹti rẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹrin àti ogún náírà (N4020). Àwọn sinima ṣe àfihàn àwọn fíìmù yìí ní ọdún 2024.

ÀWỌN OHUN TÍ A FI MỌ BÍ OWÓ TIKẸTI ṢE RÍ GANGAN

Ọpẹ Ajayi, ẹni tí ó dà Cinemax silẹ tí ó jẹ olùdarí àgbà tẹ́lẹ̀ ní Genesis Cinema kò fi ìkan pe méjì nígbà tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá  lénu wò lórí nkan ti Yinka Ade-Aluko sọ.

“N kò rò pé ẹnì ti o sọ ọrọ̀ yìí ṣe ìwádìí gidi, ó dàbí pé ó fẹ́ jẹ́ kí àwọn ènìyàn fi mọ ohun síi ni,” báyìí ni Ajayi ṣe wí.

Patrick Lee, ẹni tí ó mọ̀ nípa isafihan fíìmù sọ pé lílo owó oṣù ìjọba tó kéré jù láti fi mọ iye owó Tikẹti kò dára.

Ó sọ pé ọ̀rọ̀ tí Ade-Aluko sọ túmọ̀ sí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí sinima ni ó máa ń gba owó oṣù ìjọba tó kéré jù.

“Irú àwọn ènìyàn wo ni wọn máa ń lọ sí sinima? Mo gbà pé àwọn ènìyàn tí wọn kò ní owó pupọ tí wọn kò sì tọrọ jẹ, tí wọ́n ní owó tí wọn lè fi gbádùn ló lè lọ,” báyìí ni Ajayi ṣe sọ.

“Ṣé a gbà pé ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgbọ́n náírà ni owó oṣù ìjọba tó kéré jù ní Nàìjíríà? Àìsí àwọn ohun tí ó lè jẹ́ kí a mọ òótọ́ kò jẹ́ kí ó seese láti lè sọ pé owó yìí ni owó oṣù ìjọba tó kéré jù. Kò tún jẹ́ kí a lè fi owó oṣù ní Nàìjíríà we ti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.”

Ayẹwo tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí nípa àwọn orílẹ̀ èdè, iye owó Tikẹti, ọdún tí àwọn sinima gbà á lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yóò jẹ́ kí a mọ bí ọ̀rọ̀ sinima àti fíìmù ṣe rí.

Orílẹ̀ èdè Lebanon ni Tikẹti ti wọn jù. Orílẹ̀ èdè tí ó tẹle Lebanon ni Cambodia. Lẹ́hìn èyí ni Orílẹ̀ èdè Mali àti Kenya ni Áfíríkà (Africa).

Nàìjíríà ló tẹle àwọn orílẹ̀ èdè tí a mẹ́nuba yìí. Èyí túmọ̀ sí pé kì í ṣe Nàìjíríà ni owó Tikẹti ti wọn jù bí Ade-Aluko ṣe wí.

WÀHÁLÀ TÓ SO MỌ TÍTA TIKẸTI

TheCable ṣe àyẹ̀wò iye àwọn ènìyàn tó ń lọ wo fíìmù àti iye àwọn ènìyàn tó wà ní Nàìjíríà.

A gbà àwọn nọ́mbà tí a fi ṣe àyẹ̀wò yìí lọ́wọ́ Inside Nollywood. Eléyìí fi iye àwọn ènìyàn tó lọ sinima lọ wo fíìmù láti ọdún 2015 sí ọdún 2023 yé wa. A wá wo àwọn nọ́mbà yìí pẹ̀lú àwọn tí Statista gbé kalẹ.

A ṣe ìwádìí pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ènìyàn kan tí ó bá lọ sí sinima lọ wo fíìmù lè lọ sí sinima ju ìgbà kan lọ, ó sì lè ra Tikẹti bíi ìgbà méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ọdún kan.

Ayẹwo wa fi ye wa pé àwọn ènìyàn máa ń lọ sí sinima ní Nàìjíríà dáadáa láti wo fíìmù. Ní ọdún 2023, ìdá bíi méjì àwọn  ènìyàn tí ó wà ní Nàìjíríà tí iye wọn tó igba àti ogún ó lé mẹ́fà miliọnu (226 million) fún ọdún 2023 ni wọn lọ sí sinima láti wo fíìmù.

Afiwe tí a ṣe fihan pé àwọn sinima ní Amẹ́ríkà ta Tikẹti tí iye rẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rin àti àádọ́ta ó dín ìkan miliọnu ó lé ní ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀ta ó dín méjì àti ẹgbẹ̀ta ó lé ní ẹgbẹ̀ta àti ìkan (849,598,661) ní ọdún 2023. Iye àwọn ènìyàn tí wọn wà ní Amẹ́ríkà ní 2023 tó bíi ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà mẹta àti ogójì dín ìkan miliọnu àti ẹgbẹ̀rún miliọnu kan ó dín ní miliọnu mẹ́rin àti ẹgbẹ̀ta ó dín ní mẹtadinlogoji (339,996,563). Àwọn sinima yìí rí èrè tó lé ní ìdá ìgbà owó tí wọn fi ṣe ọrọ ajé lára àwọn ènìyàn yìí.

Ní ọdún 2022, àwọn tí a mọ sí box office ni Orílẹ̀ èdè India ta Tikẹti tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹsan miliọnu (981 million).

Nàìjíríà kò tíì ta Tikẹti tó tó báyìí rárá rí bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn ènìyàn sọ pé Nàìjíríà ni Orílẹ̀ èdè kejì tí ó ń ṣe tàbí gbé fíìmù jáde jù ní àgbáyé.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ

Àwọn àyẹ̀wò tí a ṣe fi ye wa pé ọ̀rọ̀ tí Ade-Aluko sọ yìí kìí ṣe òótọ́.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.