Àtẹ̀jade kan tí ó ṣàlàyé ìdí tí àwọn olùdíje ipò ààrẹ mẹtẹta wọnyi fi jáde fún ìdíje naa, ni àwọn ènìyàn ń pín káàkiri orí ẹ̀rọ ayélujára.
Àtẹ̀jáde yìí, tí wọn ni Sanusi Lamido Sanusi, ẹni tíí ṣe ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ ri ile ifowopamo apapọ ni Naijiria, kọ, daba pé àwọn olùdíje yìí kò sí nínú ìdíje náà torí owó.
Advertisement
“Oun kàn pàtàkì nípa àwọn mẹtẹta yíì tí wọn du ipò ààrẹ, ni wípé, ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu won ò ṣeé nítorí owó,” ìpínrọ àkọ́kọ́ nínú àtẹ̀jáde náà wí.
Àtẹ̀jáde yìí gbé àhesọ pé Atiku Abubakar, olùdíje ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú alatako Peoples Democratic Party (PDP), ti kó owó jẹ ‘dáadáa’, ó kàn fẹ́ wá dáhùn àkọlé ‘ààrẹ’ lọ́nàkọnà ni.
Àhesọ míràn wípé Bola Tinubu, olùdíje ipò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), kàn fẹ́ mú ibarajẹjẹ rẹ̀ ṣẹ ni.
Advertisement
“Ní òpin ọjọ́, yóò kọ́wa oun tó túmọ̀sí láti jẹ oníwà ìbàjẹ́ paraku,” àtẹ̀jáde náà wí.
Nípa Peter Obi, olùdíje ipò ààrẹ Labour Party, àtẹ̀jáde náà sọ wípé gómìnà Ipinle Anambra teleri náà jẹ́ ènìyàn tó ní itẹlọrun, tí ó sí fẹ́ gba orilẹ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ lọ́wọ́ àjálù burúkú, tí ó bá dé ipò ààrẹ l’ọdún 2023.
Àtẹ̀jáde yìí, tí o bẹ̀rẹ̀ sí ní k’àlè k’áko láti ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹfà, ni àwọn olùmúlò ojú òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook àti ìkànnì abẹ́yẹfò Twitter sàtúpín lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
Ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹfà, ojú òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Facebook kan ló sàtúpín àtẹ̀jáde yì. Ojú òpó yìí tí ń jẹ́ CeleSylv Updates ní òntẹ̀lẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ̀ta àbọ̀. Àwọn olùmúlò sí tí sàtúpín àtẹ̀jáde náà ní ọ̀nà ẹgbẹrun mẹta, wọn sí tí bu ọwọ́ ìfẹ́ lu ní ìgbà ẹgbẹ̀sán pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìwòye eedegbeje lekan.
Advertisement
Olùmúlò ìkànnì abẹ́yẹfò kan, Fame Kid, fi àtẹ̀jáde yìí si ojú òpó rẹ̀ ní ago méjì àbọ òkú ìṣẹjú kan, lọ́jọ́ náà, àwọn olùmúlò míràn sàtúpín rẹ lọ́nà eedegbeje o lekan, wọ́n sì bu ọwọ́ ìfẹ́ lú ní ọ̀pọ̀ ìgbà.
https://twitter.com/famekid_/status/1538519242655555584?s=20&t=9wRjATKfnfh2_ZhgYkcI7A
Max Vayshia, olùmúlò míràn, tó fi àhesọ yìí si ojú òpó rẹ̀, ti ní àtupín lọ̀nà ẹ̀ta-dín-ní-ojì dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rún (873), wọ́n sì ti bù ọwọ́ ìfẹ́ lu ní ìgbà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́je (1,300), ó sì tún ní ẹ̀ta dín ní ọgọ́ta, ọ̀rọ̀ ìwòye.
Listen, there has been NO better description of the 3 Presidential aspirants than this. I promise you, you won't be getting a better description of Peter Obi, Jagaban and Atiku. Sanusi is SPOT ON on this. READ👇🏾 pic.twitter.com/ILLUu34otH
Advertisement— Maxvayshia™ (@maxvayshia) June 19, 2022
Advertisement
I just saw this flying around, Have you read the way Mohammad Sanusi described the three presidential candidates!
Atiku | tinubu | Peter ObiAdvertisementI can see some comments online backlashing the post. Whichever way the post is 100% truth.
It is left for us to make our own decisions. pic.twitter.com/0C9TY0xbYG
Advertisement— Hauwa (@hauwaladisanusi) June 19, 2022
https://twitter.com/austine_okpegwa/status/1538592999638171653?s=20&t=lPfxJsrkWrdQIcHcMU-5Uw
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣàmúlò ojú òpó ìkànnì yìí lọ gba ìròyìn náà gbọ́, èyí tí ó hàn gbangba nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìwòye tí wọn ti n gboriyin fún ònkòwé fún ìtú sí wẹ̀wẹ̀ ọ̀rọ̀ náà.
Iṣamudaju
Àyẹwò TheCable lórí ayélujára fihàn pé kòsí ilé iṣẹ ìròyìn tótó gbẹ́kẹ̀lẹ́ kan-kan tó gbé ìròyìn yìí.
Ní ìgbà tí TheCable kàn sí Sanusi, ó sọ pé àtẹ̀jáde náà kò wá láti ọ̀dọ̀ oun. “Òfègè ni àtẹ̀jáde yìí, kìí ṣe ọwọ́ mi ló ti wá,” Sanusi sọ fún TheCable.
Àbájáde Ìwádì
Ẹ̀tàn jẹ lásán ni àtẹ̀jáde tí ó ṣ’àyẹ̀wò oun amóríyà fún àwọn olùdíje ipò ààrẹ mẹtẹta wọnyi. Sanusi Lamido Sanusi kọ́ ló kọọ́.
A kọ ìròyìn yìí ni àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Report for the World, ètò àgbáyé tí ń ṣe àtìlẹ́yìn iṣẹ́ ìròyìn tiwa-n-tiwa.
Add a comment