--Advertisement--
Advertisement

Ṣé Sylva lọ kí Diri lórí àṣeyọrí rẹ̀ nínú ìdìbò gómìnà Ìpínlẹ̀ Bayelsa

Fídíò Timipre Sylva, minisita fún ọ̀rọ̀ epo rọ̀bì tẹ́lẹ̀rí níbi tí ó ti ń gba ọwọ́ pẹ̀lú Douye Diri, gómìnà Ìpínlẹ̀ Bayelsa ni a ti rí ní orí ayélujára.

Gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn tí wọ́n fi fídíò náà síta ṣe wí, Sylva ń kí Diri kú àseyege lẹ́hìn tí Diri ṣe àṣeyọrí nínú ìdìbò gómìnà Ìpínlẹ̀ náà.

Diri, ẹni tí ó díje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) ní ìbò ẹgbẹ̀rún ní ọna àádọ́rin ó lé ní márùn-ún àti ìgbà ó dín mẹrin, eléyìí tí ó  jẹ́ kí ó fi idi Sylva, ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ẹni tí ó ní ibo ẹgbẹ̀rún ní ọna ọgọ́rùn-ún àti mẹwa àti ọgọrun ó lé ní mẹjọ rẹmi.

Àwọn ènìyàn ti pín fídíò yìí ní orí àwọn ohun ìbáraẹnise, pàápàá jù lọ ní orí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise alámì krọọsi (X, formerly called Twitter). Àwọn ènìyàn wò púpọ̀, wọ́n sì sọ̀rọ̀ gan-an nípa rẹ̀.

Advertisement

“Olóyè Timipre Sylva, oludije nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ rí gómìnà Douye Diri tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láti kíi kú àṣeyọrí. Ẹ má para yín lórí ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ wo àwọn tí wọn ti kú lásán. Èyí bani nínú jẹ́,” olumulo X kan tí ó pín fídíò yìí ni ó kọ ọ̀rọ̀ yìí.

Nínú fídíò tí àwọn ènìyàn pín kiri púpọ̀ yìí, wà rí Sylva ní ibi tí ó ti ń gba ọwọ́ pẹ̀lú Diri nígbà tí minisita náà ń sọ̀rọ̀ tí a kò gbọ́.

Olumulo X míràn kọọ pé: “Olóyè Timipre Sylva, oludije inú ẹgbẹ́ APC lọ kí gómìnà Douye Diri ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fún àseyege. Àwọn tí ó kú nígbà #BayelsaDecides2023, idije fún ìbò kú lásán. Ohun tí ó jẹ́ kí èyí dáa ni pé Diri yóò kọju mọ ètò idagbasoke Ìpínlẹ̀ yii.”

Advertisement

IDI TÍ Ó ṢE ṢE KÓKÓ LÁTI WÁDÌÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Biotilẹjẹpe kò sí ọ̀tá ìgbà pipẹ, Sylva àti Diri bára wọn fa wàhálà nípa àbájáde ìbò gómìnà Ìpínlẹ̀ Bayelsa.

Ní ọjọ́ idibo, Diri fi ẹ̀sùn kan Sylva pé ó fa wàhálà nígbà àwọn ètò ìdìbò.

Timipre Sylva ti jẹ́ oníwà ipanle ní gbogbo ìgbà ìdìbò. Tí ó bá rántí, olórí àwọn ọmọ ìlú Ijaw, alàgbà Edwin Clark, kọ lẹ́tà síi pé kí ni ìdí tí ó kọ̀ láti dẹkun ìwà ipanle rẹ̀ láti lè jaweolubori nínú ìdìbò? Diri ni ó sọ báyìí lẹ́hìn ìgbà tí ó dibo.

Advertisement

“Àmọ́sá, Ọlọ́run wà lórí ìtẹ́, a sì máa gbógun ti ìwà idaluru rẹ̀ nígbà ìdìbò.

Sylva sọ pé PDP ni ó máa ń da ìlú rú nígbà ìdìbò. Ó tún sọ pé “àwọn agbófinró ń ṣe àtilẹyin fún PDP.

Advertisement

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà ni PDP fà tí wọn sì dẹruba àwọn oludibo pẹ̀lú àwọn agbófinró. Àwọn ènìyàn wa gbàgbọ́ pé ìdíje fún ìbò yìí kò wáyé láàárín APC àti PDP, wón ní àwọn agbófinró ni APC ń kojú rẹ̀,” Sylva ló sọ báyìí.

ÌWÁDÌÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Advertisement

TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yìí, esi tí a rí fi yé wa pé àwọn kan tí ó ń jẹ́ GbaramatuVoiceTv lórí Tiktok, ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń múra wọn lára yá ló gbé ọ̀rọ̀ yìí.

GbaramatuVoiceTv fi fídíò náà síta ní oṣù karùn-ún, ọdún 2023, oṣù mẹ́fà kí wọ́n tó dibo gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Bayelsa.

Advertisement

Fídíò yìí ní àkòrí tí ó sọ pé: “Timipre Sylva lọ sí ibi ìsìnkú bàbá Douye Diri ní Sampou.”

Bàbá Diri, olóògbé Ábúráhámù (Abraham), ẹni tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkọ́ tí ó sì ti fẹhinti lẹ́nu iṣẹ́. Ó kú ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù kejì, ọdún 2023. Ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdinlaaadọrun (88 Years) nígbà tí ó kú. Wọ́n sin-ín ní ọjọ́ kẹfà, oṣù karùn-ún, ọdún 2023.

Akanti GbaramatuVoiceTv lórí TikTok ní àwọn nkan bíi ìgbéyàwó àti àwọn àjọṣe mìíràn.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SI

Fídíò yìí ti pẹ́. Kìí se ìkíni àṣeyọrí láti ọwọ Sylva sí Diri fún ṣíṣe àseyege nínú ìdìbò gómìnà.

Wọ́n ṣe fídíò yìí ní oṣù karùn-ún, ọdún 2023 nígbà tí Sylva lọ bá Diri kẹ́dùn nígbà tí bàbá rẹ̀ kú.

Diri ti gbóríyìn fún àjọ tí ó ṣètò idibo náà. Àmọ́, APC fárígá. Wọ́n ní àwọn kò gba àbájáde ìdìbò náà

Wọ́n ní kí INEC, àjọ tí ó ń ṣètò ìbò ní Nàìjíríà ṣe àyẹ̀wò èsì ìbò náà láàárín ọ̀sẹ̀ kan.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.