--Advertisement--
Advertisement

Ṣé wọ́n ti ṣí Hushpuppi ṣílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n?

Fídíò kan tí àwọn ènìyàn ń pín ní orí àwọn ohun ìbáraẹnise (Social media) tí sọ pé Ramon Abbas, tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Hushpuppi tí kúrò ní ẹ̀wọ̀n.

Àwọn ènìyàn mílíọ̀nù méjì ó dín ọgọ́rùn-ún lo wòó. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì àti irínwó lo pín in. Àwọn ènìyàn tí ó ju ẹgbẹ̀rún méje lo fẹ́ràn fídíò yìí lórí ohun ìgbàlódé alami krọọsi (X, tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀).

Àkòrí fídíò náà tí @praiseoghre pín sọ pé: “wọ́n ti ṣí Hushpuppi ṣílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n. Ẹ jẹ́ ka gbà pé ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ nínú àṣìṣe rẹ̀.

Nínú fídíò yìí, àwọn ènìyàn ń kí Hushpuppi kaabọ níbi tí àwọn ènìyàn tí ń wọ ọkọ̀ Òfurufú. Ó gbé baagi kan dání.

Advertisement

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú fídíò náà ni ó ń yàá pẹ̀lú fóònù (ẹ̀rọ alagbeka) bí ó ṣe ń kúrò ní ibi tí wọ́n tí ń wọ ọkọ̀ Òfurufú naa.

Àwọn ènìyàn ti pín fídíò náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú ìwé lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọrẹ (Facebook). Wọ́n ní Hushpuppi ti jáde ní ẹ̀wọ̀n.

TA NI HUSHPUPPI?

Hushpuppi jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tí ó jẹ́ gbajumọ orí ayélujára tí ó ń ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kànlá ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fún ìwà jìbìtì orí ayélujára.

Advertisement

Wọ́n fi ẹ̀sùn pípe ara rẹ̀ ní nkan tí a mọ ẹlòmíràn sì láti lè lu àwọn ènìyàn ní jìbìtì owó tí ó tó aadọsan dín méjì biliọnu náírà.

Ní ọdún 2020, wọ́n sọọ, wọ́n sì múu ní ibi tí a mọ̀ sí Dubai ní orílẹ̀-èdè United Arab Emirates (UAE).

Otis Wright II ni orúkọ adajọ tí ó sọ sí ẹ̀wọ̀n nígbà tí wọ́n fi òfin gbé e lọ sí Amẹ́ríkà ní oṣù keje, ọdún 2020.

Adajọ náà sọ pé kí ó sàn owó kabiti fún ìtanràn fún lílu àwọn ènìyàn méjì ní jìbìtì lẹ́hìn ìgbà tí ó gbà pé ohun jẹ ẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan án fún fífi ọwọ́ so ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn láti lu jìbìtì ní oṣù kẹrin, ọdún 2021.

Advertisement

Ó wà ní keremọnje ní ibi tí ó ti ń ṣe ẹ̀wọ̀n ní ibi tí a mọ̀ sí Federal Correctional Institution (FCI), ní Fort Dix, New Jersey, ní Amẹ́ríkà.

ÌWÁDÌÍ

Advertisement

Àyẹ̀wò tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe fi hàn pé wọ́n ti fi fídíò yìí sí orí YouTube, ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti máa ń pín àwòrán ní ọdún 2018.

Àwọn tí ó fi síbẹ̀ ni a mọ̀ sí iLiteTv, nígbà ọjọ́ ìbí Hushpuppi ní orílẹ̀-èdè Cyprus.

Advertisement

Fídíò náà tún jẹyọ lórí YouTube ní ọdún 2020, nígbà tí wọ́n múu. Fídíò náà sì sọ pé wọ́n ti túu sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n.

Láti lè mọ ibi tí Hushpuppi wà, TheCable wo rẹkọọdu àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti US Federal Bureau of Prisons.

Advertisement

Rẹkọọdu náà ní orúkọ, ọjọ́ orí, ibi tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n wà àti ìgbà tí wọ́n máa fi wọ́n sílẹ̀.

Àbájáde àyẹ̀wò yìí fi hàn pé ibi tí Hushpuppi wà ni wọ́n ń pè ní Fort Dix Federal Correctional Institution. Ìgbà tí wọ́n yóò fi sílẹ̀ ni oṣù kẹrin, ọdún 2029.

BÍ A SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ

Wọ́n kò tíì fi Hushpuppi ṣílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n. Fídíò yìí ti wà níta láti ọdún 2018.

Rẹkọọdu tí a yẹ̀wò fi yé wa pé ó sì í ń ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kànlá lọ́wọ́.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.