--Advertisement--
Advertisement

Amófin sọ pé ibanibimọ lòdì sí òfin ní Nàìjíríà. Ṣé òótọ́ ni?

Sonnie Ekwowusi, amòfin tí ó tún máa ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn, sọ pé bíbá ẹlòmíràn bímọ tàbí ìbáẹlòmíràn-bímọ (surrogacy) jẹ́ nǹkan tó lòdì sí òfin ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ kejilelogun, oṣù kẹrin, ọdún 2024, nígbà tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò lórí ètò kan tí a mọ̀ sí the Morning Show (ètò òwúrọ̀) lórí ẹ̀rọ amóhunmáwòrán Arise Tv.

Amòfin náà sọ pé ìbánibímọ lòdì sí òfin nítorí pé abánibímọ (surrogate) “ń fi ikùn rẹ̀ pa owó”tí ó sì máa gbé ọmọ fún ẹni tí ó bá bímọ. Ó fi kún un pé ètò yìí máa dín iyì obìnrin kù.

“Ní àkọ́kọ́, ètò kí obìnrin kan bá obìnrin tàbí tọkọtaya bímọ kò bójú mu, ó sì lòdì sí òfin. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọn kò mọ̀ pé ó lòdì sí òfin,” amòfin náà ló wí báyìí.

Advertisement

“Ìbánibímọ túmọ̀ sí pé pípo ẹyin obìnrin àti nǹkan ọkùnrin tó máa ń di ọmọ pọ̀ tí wọ́n sì máa fi sínú obìnrin. A máa ń pèé ní ìfinúpawó. Abánibímọ yìí yóò gbé oyún náà fún oṣù mẹsan, á bímọ, á sì gbe fún ẹni tí ó bá bímọ tàbí ẹni tí ó fẹ́ ọmọ.

“Abánibímọ kan náà yìí máa lọ ṣe irú èyí fún obìnrin tó ń wá ọmọ mìíràn. Abánibímọ yìí kàn jẹ́ ohun èlò. Ìdí rèé tí àwọn ènìyàn fi máa ń sọ pé ohun tí Abánibímọ ń ṣe yìí kò buyì kún obìnrin.”

Amòfin yìí tọ́ka sí apá ọgbọ́n, abala kìíní Òfin ẹ̀tọ́ ọmọdé (Child Rights Act) láti fi kin tàbí ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.

Advertisement

Apá kẹta òfin kan náà sọ pé ìjìyà àtìmọ́lé ọdún mẹwa ló wà fún ẹni tí ó bá tàpá sí abala Kínní òfin yìí.

“Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ rà, tà tàbí fi ọmọ pa owó tàbí ṣòwò tàbí fi ọmọ sọ́dọ̀ lọ́nà tí kò yẹ,” báyìí ni apá kẹta yìí ṣe wí.

“Ẹni tí ó bá ṣe nǹkan tó lòdì sí abala Kínní òfin yìí rú òfin, yóò sì lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹwa gbára.”

Ó tọ́ka sí apá àádọ́ta òfin ètò ìlera tí ó lòdì sí lílo ohun ìgbàlódé (technology) láti rán ènìyàn lọ́wọ́ láti bí ọmọ.

Advertisement

“Ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ ṣe àyípadà ohun tí a bímọ́ ènìyàn (genetic characteristics) tàbí se àtúnṣe ohun tí ó máa ń di ọmọ láti lè sọ ọ́ di ènìyàn,” bayii ni apa òfin yìí ṣe wí.

“Ẹni tí ó bá tàpá sí òfin yìí, yóò fojú ba ilé ẹjọ́, yóò sì ṣe ẹ̀wọ̀n tí kò kéré ju ọdún márùn-ún láì sí àní-àní.”

Ọ̀rọ̀ tí amòfin yìí sọ jẹ́ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ ọ̀rọ̀ lorisirisi nípaohun tí òfin sọ nípa ìbánibímọ.

Advertisement

KÍ NI ÌBÁNIBÍMỌ?

Ìbánibímọ jẹ́ ètò tí àwọn ènìyàn máa ń ṣe tí obìnrin kan (surrogate) máa bá obìnrin tàbí obìnrin àti ọkọ rẹ̀ lóyún tí ó sì máa bíi fún wọn.

Abánibímọ yìí máa lóyún ní ọ̀nà ìlóyún ìmọ̀ sayẹnsi (Invitro Fertilisation-IVF). Tí a bá fẹ́ ṣe eléyìí, a máa mú ẹyin obìnrin, a máa loo pọ pẹlu nǹkan ọmọ ọkùnrin-spaamu (sperm), eléyìí ló máa di ọmọ.

Ọ̀nà méjì ni wọ́n máa ń gbà ṣeé. Ọ̀nà kinni ni pé kí a mú spaamu àti ẹyin ọmọ ti obìnrin, a sì máa daa pọ̀, a sì máa fi sínú obìnrin miran (abanibimọ), yóò sì gbé eléyìí títí yóò fi bímọ.

Ọ̀nà kejì ni lílo spaamu àti ẹyin abanibimọ láti lè sọ di ọmọ. Abanibimọ yìí yóò gbé oyún yìí títí yóò fi bíi fún ọkùnrin àti obìnrin tó ni ọmọ.

Ìbánibímọ pín sí ọna méjì. Ona kìíní ni pé abanibimọ lè gba owó. Ọ̀nà kejì ni pé abanibimọ kò ní gba owó. Kí ìbánibímọ tó wáyé, àdéhùn tí òfin tí lẹ́yìn gbọ́dọ̀ wà.

KÍ NI ÒFIN ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ SỌ NÍPA ÌBÁNIBÍMỌ?

Ètò yìí jẹ́ ohun tó le. Ìdí rèé tí àwọn orílẹ̀-èdè kan kò fi ní òfin nípa rẹ̀. Nàìjíríà náà kò ní òfin fún ètò yìí.

Ní ọdún 2016, àwọn asòfin kan ṣe àgbékalẹ̀ ètò tó lè di òfin tí a lè fi da rí lílo tẹkinọlọji (technology) láti ran ènìyàn lọ́wọ́ láti bímọ (assisted reproductive technology-ART) níwájú ilé ìgbìmọ̀ asòfin. Àmọ́ kò tíì di òfin.

Àmọ́sá, ìlú Èkó ṣe àgbéjáde ìtọ́nisọ́nà ètò yìí, eléyìí tó jọ mọ́ òfin fún irú ètò yìí.

ART jẹ́ ètò ọmọ bíbí tí a ti máa ń mú ẹyin obìnrin tí ó ń wá ọmọtí a máa lò pọ̀ pẹ̀lú spaamu ọkùnrin ní laaabu (laboratory), a sì máa fi èyí sínú obìnrin abanibimọ, eléyìí ni obìnrin abanibimọ máa gbé gẹ́gẹ́bí oyún tí ó sì máa bí.

ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ

Láti lè mọ bóyá ètò yìí lòdì sí tàbí bá òfin mú ní Nàìjíríà, TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn amòfin sọ̀rọ̀ láti lè mọ bí wọ́n ṣe rí ọ̀rọ̀ yìí sí.

Henry Akanwa, ẹni tí ó jẹ amòfin, sọ pé ètò yìí di ohun tí kò bá ojú mu tí wọ́n bá san owó fún abanibimọ. Eléyìí tí àwọn òyìnbó ń pè ní ‘child trafficking.’

“Ètò yìí kìí ṣe ohun tí kò bá ojú mu tí ènìyàn kò bá san owó fúnabanibimọ láti gba ọmọ tó bí fún ní, ìjọba lè ka eléyìí sí child trafficking,” Akanwa ló sọ báyìí.

“Tí ènìyàn bá bímọ láìṣe ìgbéyàwó, tí ó sì fẹ́ fún ẹlòmíràn ní ọmọ yìí, àwọn tọkọtaya lè fẹ́ gba irú ọmọ yìí gẹ́gẹ́bí ọmọ wọn. Wọn á sì ṣe ohun tí òfin sọ. Obìnrin tí ó bá àwọn ẹlòmíràn bímọ ti di abanibimọ nítorí pé ó bímọ, ó sì fún ẹlòmíràn ní ọmọ náà,”

Olu Daramola, amòfin àti agbẹjọ́ró àgbà (Senior Advocate of Nigeria-SAN) sọ pé ètò yìí kò lòdì sí òfin nítorí pé òfin kò sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Ó ní ohun tí òfin bá lòdì sí ni kò bá òfin mu.

“Kò sí òfin fún ètò yìí ní Nàìjíríà. Ìyàtọ̀ wà láàárín kí òfin lòdì sí nǹkan àti kí òfin máa ṣe àgbékalẹ̀ nnkan. Lọ́wọ́lọ́wọ́, kò sí òfin tí ó sọ pé ènìyàn lè ṣé tàbí ènìyàn kò lè ṣé ìbánibímọ,” amòfin yìí ló sọ bayii fún TheCable.

“Àgbékalẹ̀ òfin ọ̀tọ̀ ló wà fún child trafficking. Tí o bá wo òfin tó wà fún èyí (Child’s Rights Act), òfin yìí dáàbò bo àwọn ọmọ tí àwọn ènìyàn ti bí. Ètò ìbánibímọ kìí ṣe kí a gba ọmọ ẹlòmíràntọ́ kí a sì tọ́jú rẹ̀ bíi ọmọ ẹni. Ìbánibímọ ni kí ẹlòmíràn bá ẹni tí kò lè bímọ bí ọmọ,” Daramola ló sọ báyìí.

Ó ní kí a lè mú òpin bá àríyànjiyàn ìbánibímọ, ìjọba gbọ́dọ̀ dá síi.

“Ohun tí a lè ṣe ni pé kí ìjọba gbà pé ètò yìí wà, kí òfin sì wà fún un nítorí pé nítorí àwa ènìyàn ni òfin ṣe wà, kìí se nítorí òfin ni àwọn ènìyàn ṣe wà. Òfin gbọ́dọ̀ mọ ipa tí ìlọsíwájú tẹkinọlọji lè kó nínú ayé àwọn ènìyàn, kìí se gbogbo ohun tí kò bójú mu ni òfin lòdì sí,” àlàyé amòfin yìí ni èyí.

Olutumbi Babayomi, amòfin nípa ọ̀rọ̀ ẹbí sọ pé ènìyàn kankan kò lè gbé ènìyàn kan lọ sí ilé ẹjọ́ nítorí pé ó tàpá sí “òfin tí kò sí.”

“Ní ọjọ́ èní, kò sí òfin kankan fún ètò yìí. A kò lè gbé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan irú báyìí lọ sí ilé ẹjọ́,” Babayomi ló sọ báyìí.

“Ìkan lára àwọn ìṣòro tí a ní ní Nàìjíríà ni pé a máa ń sòfin. Àmọ́, a kìí ṣe bí àwọn tó bá tàpá sòfin yóò ṣe jìyà ìwà wọn. Kí a tó lè sọ pé ohun kan lòdì sí òfin, ó jẹ́ ìwà tí kò dára. Àmọ́, a kò ní òfin tó lè sọ pé ìwà tí kò dára ni ètò yìí.

Ó sọ pé àsìkò láti ṣe òfin fún ètò yìí kò tíì tòó nítorí pé ohun tó so mọ́ọ pọ̀.

Ó ní tí ọ̀rọ̀ yìí bá dé ilé ẹjọ́, ilé ẹjọ́ kò nìí ríi bíi ìbánibímọ. Wọ́n máa ríi bí ifiọmọsowo.

Ó ní Child Rights Act àti National Health Act kò lòdì sí ìbánibímọ.

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢÍ

Kò sí òfin kankan fún ètò ìbánibímọ. Child Rights Act and National Health Act kò sọ pé kò dára.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.