Nínú ifọrọwanilẹnuwo tí Arise TV ṣe pẹ̀lú Atiku Abubakar, olùdíje fún ipò ààrẹ ni abẹ ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party (PDP) tí ó tún jẹ́ igbá-kejì Olóyè Olusẹgun Ọbásanjọ́, ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí ní aipẹ yìí, Atiku sọ nípa ètò ìjọba tí ó ní fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ọdún 2023.
Ìwé Ìròyìn TheCable ṣàyẹ̀wò àwọn oun tí ó sọ. Bí a se rí ọ̀rọ̀ náà sí nìyí:
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́KỌ́: Abraham Lincoln, ẹni tí ó jẹ ilumọka lára àwọn olórí ilẹ̀ Amẹ́ríkà díje fún ipò ààrẹ ní ìgbà márùn-ún sí mẹ́fà kí ó tó ṣ’àṣeyọrí.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ SÍ: Irọ ni.
Advertisement
Lincoln kò díje fún ipò ààrẹ ní ìgbà márùn-ún tàbí mẹ́fà gẹ́gẹ́bí Atiku ṣe wí.
Lincoln se aseyege ní ìgbà àkọ́kọ́ tí ó díje fún ipò ààrẹ ní ọdún 1860. Àwọn ènìyàn sì tún fi ìbò gbée wọlé ní ẹkeji ní ọdún 1864.
Ó jẹ́ Ààrẹ kẹrìndínlógún tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n pá á ní ibi eré orí ìtàgé Ford (Ford’s Theatre), ní Washington DC, tí ó jẹ olú ìlú ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní agọ John Wilke. Ó kú ní ọjọ́ kẹdogun, osù kẹrin, ọdún 1865, ọjọ́ kejì tí àwọn apànìyàn ṣe ikú pá.
Ọ̀RỌ̀ KEJÍ: Kò sí òfin tí ó ní wí pé òṣìṣẹ́ ìjọba kò lè se owo tàbí karakata.
Advertisement
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ SÍ: Irọ ni.
Abala kẹfà, ètò òfin fún bí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tàbí àwọn olóṣèlú tí a yàn fún isẹ isejọba se gbọ́dọ̀ máa hu ìwà tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi ye wa pé oun kan soso tí òfin fi àyè gba àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti se ni iṣẹ́ ọ̀gbìn yálà fún jíjẹ tàbí ọlọpọ yanturu fún títà.
Ètò Agbekalẹ yìí tún wà ní abala kejì, apakan àkọ́kọ́ àti apakan èkejì ti ìwé òfin/ìṣejọba ti ọdún 1999.
Timi Olagunju, Amofin tí ó tún jẹ́ Oluyanju imulo sọ fún ìwé ìròyìn TheCable pé abala kẹfà ìwé òfin bí àwọn òṣìṣẹ́ se gbọ́dọ̀ máa hùwà àti ilé ẹjọ tí a ti ń da ẹjọ fún àwọn osisẹ tí kò bá hu ìwà dáadáa kò fi ìkan pe méjì nípa ọ̀rọ̀ yí.
Advertisement
Ètò bí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba se gbọ́dọ̀ máa hùwà jẹ́ òfin tí ilé asòfin se tí ó sì wà nínú ìwé òfin. Kìí se afigbalẹgbẹ tàbí àfikún rárá.
Abala Kẹfà fi ye wa pé ẹni tí ó wà ní ipò ìjọba tàbí tí ó ń se isẹ ìjọba kò gbọ́dọ̀ ní tàbí kópa nínú isẹ àdáni tàbí owo/karakata yàtọ̀sí isẹ ọgbin/agbẹ láti lè gbé isẹ ọgbin lárugẹ. Amofin náà ni ó wí báyìí.
“Ó pandandan kí a mọ pé òfin náà ṣe iyasọtọ fún/fi àyè silẹ fún nkan kan. Àyè tí ó fi sílẹ̀ yìí ni wí pé òṣìṣẹ́ ìjọba lè ní/se isẹ adani/karakata tí ó bá jẹ pé kìí se gbogbo ìgbà ni ó gbọ́dọ̀ máa lọ sí ibi isẹ ìjọba.”
Olagunju fi ye wa pé òun kò tíì rí òṣìṣẹ́ ìjọba tí a rán ní ẹ̀wọ̀n nítorí wí pé ó ní isẹ àdáni tàbí se owo/karakata ni ìgbà tí ó wà ní ẹnu isẹ ìjọba tàbí se isẹ ìjọba lọ́wọ́ láti ìgbà tí òun ti ń se isẹ Amofin.
Advertisement
Ọ̀rọ̀ :
Ọ̀RỌ̀ KẸTA: Gbogbo ènìyàn tí ó ń gbé orílè-èdè Egypt jẹ́ ọgọ́rin miliọnu àti wí pé àwọn Ọlọpa/Agbofinro orílẹ̀-èdè náà ju miliọnu méjì lọ.
Advertisement
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ SÍ: irọ ni ọ̀rọ̀ méjèèjì.
Kò sí ẹ̀rí tí ó dájú tí ó sọ wí pé àwọn agbofinro ilẹ̀ Egypt ju miliọnu méjì lọ.
Advertisement
Agbekalẹ ètò kan tí àwọn tí ó ń ṣàkóso inú orílẹ̀-èdè náà nípa àwọn jagunjagun orílẹ̀-èdè náà sọ wí pé ilẹ̀ Egypt ní bíi àwọn agbofinro ẹgbẹ̀rún ni ọna ọdunrun àti ẹgbẹ̀rún ni ọna àádọ́ta.
Gbogbo àwọn agbofinro ilẹ̀ Egypt ni osù kẹ̀sán, ọdún 2014 jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọna irinwo àti ẹgbẹ̀rún ni ọna ọgọ́ta ó dín ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹdẹgbẹta.
Advertisement
Àwọn Jagunjagun orí ilẹ̀ ìlú náà jẹ ẹgbẹ̀rún ní ọna ọdúnrún àti ẹgbẹ̀rún ní ọna ogójì. Àwọn Ajagun ofurufu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ni ọna ọgọ́rùn-ún, lára àwọn ajagun orílẹ̀-èdè náà tí a kọ bí a ti ń jagun lórí omi jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọna méjìdínlógún àti ẹdẹgbẹta pẹ̀lú àpapọ̀ àwọn ifisura tí ó jẹ ẹgbẹ̀rún ní ọna irinwo àti ẹgbẹ̀rún ní ọna ọgọ́rin ó dín ẹgbẹ̀rún kan.
Àpapọ̀ àwọn agbofinro ilẹ̀ Egypt kò tó “miliọnu méjì” tí Atiku wí.
Ayẹwo kan tí WorldAtlas se ní ọdún 2017 sọ̀rọ̀ nípa àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dàgbàsókè àti ìyè àwọn Ọlọpa tí wọn ní.
Ayẹwo yìí sọ wí pé orílẹ̀-èdè China ní o wà ní ipò àkọ́kọ́. Ìlú náà ní àwọn agbofinro miliọnu kan àti ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹgbẹ̀ta. Orílẹ̀-èdè India ni ó wà ní ipò kejì. India ní àwọn Ọlọpa miliọnu kan àti ẹgbẹ̀rún ni ọna ẹgbẹ̀ta ó dín mẹdogun pẹ̀lú ọdúnrún lé ní àádọ́ta àti mẹ́ta. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni ó wà ní ipò kẹta pẹ̀lú àwọn agbofinro ẹgbẹ̀rún ní ọna ẹdẹgbẹrun àti mẹ́ta pẹ̀lú ọgọjọ ó lé ìkan.
Kò sí orílẹ̀-èdè Egypt nínú àwọn orílẹ̀-èdè ọgbọn tí World Atlas ṣe àyẹ̀wò iye Ọlọpa tí wọn ní.
United Nations Population Fund (UNFPA), àjọ àgbáyé tí ó ń se ètò nípa iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè sọ wí pé gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Egypt jẹ́ miliọnu ọgọ́rùn-ún àti mẹ́fà ó lé ní ẹgbẹ̀rún ní ọna igba, kìí sii se ọgọ́rin miliọnu tí Atiku sọ.
Ọ̀RỌ̀ KẸRIN: Epo rọbi ni ó fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìdá ní ọna ogún iye owó tí Nàìjíríà ń rí.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ SÍ: irọ ni.
Iṣàyẹ̀wò tí ó jẹ mọ́ oun kíkà tí Statista se fi ye wa pé láàrin osù kẹwàá sí osu kejìlá, ọdún 2018 àti láàárín osù keje sí osù kẹsàn-án, ọdún 2021, iye owó tí Nàìjíríà rí ní orí/ni ara epo rọbi kò tó idamẹwa owó tí Nàìjíríà ní.
Ìwé Ìròyìn TheCable ṣàyẹ̀wò oun kika tí National Bureau of Statistics, àjọ tí ó wà ní ìdí kíkà oun àwùjọ ní ilẹ Nàìjíríà ṣe.
A ríi wí pé iye owó tí Nàìjíríà rí lára epo tí ó jùlọ láàrín ọdún 2019 àti ọdún 2021 jẹ idamẹsan àti díẹ̀ iye owó tí ó wọlé fún Nàìjíríà. Nàìjíríà rí owó tí ó jẹ idamẹsan owó rẹ yìí láàrin osù keje sí osù kẹsàn-án, ọdún 2019.
Ní ọdún 2021, iye tí Nàìjíríà rí lára epo rọbi jẹ́ ìdá méje ó lé díẹ̀ lára owó tí ó wọlé fún Nàìjíríà.
Iye tí Nàìjíríà rí lára epo jẹ́ ìdá mẹ́jọ ó lé díẹ̀ ní ọdún 2020.
Ìwé Ìròyìn TheCable rí nínú àyẹ̀wò wá pé iye owó tí Nàìjíríà rí ní ara epo dín ní idamẹwa àpapọ̀ iye owó tí ó wọlé ní ọdún kọ̀ọ̀kan nínú ọdún mẹ́ta.
Ọ̀RỌ̀ KARÙN-ÚN: Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àwọn aṣàkóso eto igbofinro mẹ́tàdínlógún. Gbogbo wọn sì ní olórí láti agbègbè ìjọba kan náà.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ SÍ: kìí se gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni òótọ́.
Ayẹwo Ìwé Ìròyìn TheCable fi ye wa pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olórí àwọn agbofinro ni a yàn láti Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Síbẹ̀síbẹ̀, díẹ̀ lára àwọn olórí àwọn agbofinro yìí jẹ ọmọ Gúsù, ilẹ Nàìjíríà. Lára àwọn yìí ni olórí Defense Intelligence Agency tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Samuel Adebayo, Lucky Irabor tí ó jẹ olórí àwọn tí ó ń dáàbò bo ìlú tí ó jẹ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Delta, Oladayo Amao, tí ó jẹ olórí àwọn ajagun ofurufu lọ́wọ́ tí ó jẹ ọmọ Ìpínlẹ̀ Ọsun.
S/N | Security agency | Head of agency | State of origin | Geo-political zone |
---|---|---|---|---|
1. | State Security Services (SSS) | Mr. Yusuf Magaji Bichi | Kano state | North-west |
2. | National Intelligence Agency (NIA) | Abubakar Ahmed Rufai | Katsina state | North-west |
3. | Defense Intelligence Agency (DIA) | Samuel Adebayo | Ekiti state | South-west |
4. | Chief of Defence Staff | General Lucky Irabor | Delta state | South-south |
5. | Nigerian Army | Faruk Yahaya (Chief of Army Staff) |
Sokoto state | North-west |
6. | Nigerian Navy | Awwal Zubairu Gambo (Chief of Naval Staff) | Kano state | North-west |
7. | Nigerian Air Force | Oladayo Isiaka Amao (Chief of Air Staff) | Osun state | South-west |
8. | Nigeria Police Force (NPF) | Usman Alkali Baba (Inspector General of Police) | Yobe State | North-East |
9. | Nigeria Customs Service | Col. Hameed Ibrahim Ali (Rtd.) | Bauchi state | North-east |
10. | Nigerian Correctional Service | Haliru Nababa (Controller-General) | Sokoto state | North-west |
11. | Nigerian Security and Civil Defense Corps (NSCDC) | Ahmed Abubakar Audi (Commandant General) | Nasarawa state | North-central |
12. | Nigeria Immigration Service | CGI Isah Jere Idris (Comptroller General of Nigerian Immigration.) | Kaduna state | North-west |
13. | National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA) | Brig. Gen. Mohamed Buba Marwa (Rtd.) | Adamawa state | North-east |
14. | Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) | Abdulrasheed Bawa | Kebbi state | North-west |
15. | Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission (ICPC) | Professor Bolaji Owasanoye SAN | Ondo state | South-west |
16. | National Security Adviser | Babagana Monguno | Borno state | North-east |
Add a comment