Àtẹ̀jáde kan lórí Facebook gbé àhesọ pé darandaran Fulani kan fi àádọta màlúù ati ẹka ilẹ̀ mẹ́ta tọrẹ fún Peter Obi, olùdíje fún ipò Ààrẹ ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
“Ọkùnrin Hausa kan, “Danladi” ọmọ Ìpínlẹ̀ Kaduna fi àádọta màlúù àti ẹka ilẹ̀ mẹ́ta ta Peter Obi lọrẹ,” ọ̀rọ̀ ìfòrí yìí ni olùmúlò ojú òpó kan kọ s’ábẹ́ àtẹ̀jáde naa.
Àwòrán méjì ló wà pẹ̀lú àtẹ̀jáde náà. Èyí tí ó wà ni apá òsì ṣ’àfihàn màlúù funfun nínú aginjù. Ní apá kejì, àwòrán míràn ṣ’àfihàn màlúù aláwọ̀ funfun àti búráùn nínú ewéko.
Advertisement
Ọkùnrin pupa kan wà nínú àwòrán kejì.
“Ó dámilójú pé tí arákùnrin yìí tí ó wá láti ìlà-oòrùn bá di ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, yóò ṣe ètò àbò tí ó kún ojú òṣùwọ̀n,” báyìí ni ìparí ọ̀rọ̀ ìfòrí náà wí, èyí tí ‘Danladi’, ọkùnrin pupa inu àwòrán náà sọ.
Olùmúlò ìkànnì ibaraẹnisọrẹ kan ti orúkọ rẹ̀ń jẹ́ ‘Obidient’, ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọlẹ́yìn tàbí olùfẹ́ràn Peter Obi fi ń pe ara wọn fi àtẹ̀jáde yìí sí ojú òpó rẹ̀ ní ọjọ́ kejìlá oṣù keje, ó ní ọ̀rọ̀ ìwòye èjì dín ní okòó-lé-ní-ẹgbẹ́ta, àwọn olumulo míràn ti bu ọwọ́ ìfẹ́ lùú ni ọ̀nà ẹgbẹ̀ẹ́dógún, wọ́n sì ti se atunpin rẹ̀ ní ìgbà ẹẹdẹgbẹrin ó lé ní ọgọrin àti mẹ́ta.
Advertisement
Àwọn ojú òpó míràn lórí ìkànnì ibaraẹnisọrẹ náà ṣ’atunpin àtẹ̀jáde yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
Olùmúlò ojú òpó tí kò ní ìfura sọ pe, “Inú mi dùn gidigan. Ọlọ́run ti bá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣé.”
Isaridaju
A lo Yandex, oun àmúlò ìgbàlódé fún àyẹ̀wò àwòrán láti fi ṣe ìwádìí orísun àwòrán yìí, ati àwọn míràn tó jọọ́, ṣíṣe itọpinpin àwòrán at’ẹyin wa (reverse image search) fihàn pé, àwòrán ọkùnrin pupa tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Danladi ti wà lórí ayélujára láti oṣù kẹta ọdún 2021.
Advertisement
Àbájáde àyẹ̀wò fihàn pé ilé ìwé ìròyìn Daily Trust lo àwòrán yìí ní ojú ìwé ayélujára wọn ni ogúnjọ́, oṣù kẹta ọdún 2021 pẹ̀lú àkòrí ìròyìn tó sọ wí pé “Dauda, Láti Isẹ Darandaran Sí Olùkọ́ Ilé Ìwé Gíga Yunifásítì.”
Tani Adamu Dauda?
Ìwé Ìròyìn Daily Trust ṣ’àfihàn arákùnrin yìí gẹ́gẹ́ bíi Adamu Dauda Garba, lòdì sí Danladi, orúkọ tí wọ́n pèé nínú àtẹ̀jáde akálékáko náà.
Ìròyìn náà gbé ìtàn bí Adamu, ẹni tí wọ́n bí ní ojọ́ kẹ̀wá, oṣù kẹ̀wá ọdún 1985, ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ darandaran ní Ìpínlẹ̀ Taraba láti ọmọ ọdún mẹ́fà àti bí ó ṣe ń kẹ́ẹ̀kọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ náà.
Advertisement
Ní ọdún 2009, arákùnrin yìí gba ìwé-ẹ̀rí ilé ẹ̀kọ́ gíga fún àwọn olùkọ́, National Certificate of Education (NCE) ní Ìpínlẹ̀ Taraba níbi tí a ti ń kọ́ni ní iṣẹ́ olùkọ́ (Taraba state college of education) ní ìlú Jalingo, èyí tí ó jẹ olú ìlú Ìpínlẹ̀ Taraba.
”Ní ìgbà tí mo parí ẹ̀kọ́ mi, àwọn ènìyàn fi tó mi létí pé, Yunifásítì ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Wukari ń wá àwọn olùṣọ́gbà, mo sì pinnu láti kọ lẹ́tà ìgbanisíṣẹ́, wọ́n sí gbà mí sí iṣẹ́,” arákùnrin yìí ló sọ báyìí.
Advertisement
L’ẹ́yìn ọdún mẹ́rin tó ṣiṣẹ́ aṣọ́gbà ni Yunifásítì náà, arákùnrin yìí di akẹ́kọ̀ọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ gíga náà níbi ti ó ti kọ́ nípa isẹ ọ̀rọ̀ àwùjọ (sociology) – wọ́n sì gbáà sí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ olùkọ́ni (graduate assistant) l’ẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tán.
Èsì Adamu sí ìròyìn òfégè
Advertisement
Ìwádìí lórí ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter) fihàn pé ìdènà ránpẹ́ kan wà lórí ojú òpó Adamu.
Àyẹ̀wò ojú òpó rẹ̀ fihàn pé ó ti fèsì sí àhesọ náà.
Advertisement
Ó ní: “Orúkọ mi ni Adamu Dauda Garba láti Ìpínlẹ̀ Taraba. Èmi kò fọwọ́sí ìmúlò àwòrán mí lórí ojú ìwé ayélujára wọn fún ìròyìn èké yìí. Mo rọ gbogbo ènìyàn kí wọ́n má ṣ’àfiyèsí ìròyìn yìí, kí wọ́n sì dúró de àbájáde ilé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí.”
https://twitter.com/ADAMUDaudaGarb2/status/1546909972239368192?ref_src=twsrc%5Etfw%7Ctwcamp%5Etweetembed%7Ctwterm%5E1546909972239368192%7Ctwgr%5E%7Ctwcon%5Es1_&ref_url=https%3A%2F%2Fwww.thecable.ng%2Fwp-admin%2Fpost.php%3Fpost%3D724194action%3Deditclassic-editor
Àbọ̀ Ìwádìí
Àbájáde ìwádìí wà fihàn pe Adamu Garba ni orúkọ ọkùnrin tí wọ́n pè ní ‘Danladi’ nínú àtẹ̀jáde yìí. Kò fi àádọta màlúù tàbí ẹ̀ka ilẹ̀ mẹta tọrẹ ní ìpínlè Kaduna fún Peter Obi, olùdíje fún ipò ààrẹ. Irọ́ gbáà ni àhesọ náà.
Add a comment