Atẹjade kan lórí àwọn ohun ibaraẹnise ìgbàlódé (social media) sọ pé àwọn sójà (soldiers) tí kọlu Okuama, ibì kan ní ìpínlẹ̀ Delta láti gba ẹ̀san pípa tí àwọn ará agbègbè náà pa àwọn sójà mẹrindinlogun ní ìpínlẹ̀ náà.
Fídíò yìí, èyí tí àwọn ènìyàn ti pín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn sọ pé fídíò nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni.
Ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kẹta, ọdún 2024, àwọn ọ̀dọ́ ní Okuama pa sójà mẹrindinlogun kan (lieutenant colonel kan, major méjì, captain kan àti àwọn méjìlá mìíràn ). Wọ́n rán àwọn sójà yìí ní iṣẹ́ lọ sí Okuama ni lati lọ yanjú wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.
Ikú àwọn sójà yìí fa wahala àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sùn káàkiri Nàìjíríà. Lára àwọn ẹ̀sùn yìí ni èyí tó sọ pé àwọn sójà yìí gba ẹ̀san nípa dídáná sun Okuama láti sọọ́ di ilẹ̀.
Advertisement
“Àwọn sójà ń sọ Okuama di ilẹ̀ ní àárọ̀ yìí. Àwọn òṣìṣẹ́ ológun tí múra láti kọlu agbègbè náà,” @EmekaGift100, lára àwọn tí ó ń lo X (tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀rí) ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń pín fídíò yìí. X jẹ́ ohun ìgbàlódé ibaraẹnise.
Olumulo X yìí sọ pé ajafun ẹtọ àwọn ènìyàn ni òhun, òhun sì tún jẹ́ ẹni tí ó ń tún bí a ṣe mọni sí ní àwùjọ fún àwọn ajija òmìnira tí a mọ̀ sí Indigenous People of Biafra (IPOB) ṣe. Àwọn ènìyàn sọ pé àwọn ohun tí ìjọba kò fi àyè gbà ni àwọn nǹkan tí IPOB ń ṣe.
Àwọn ènìyàn wo Atẹjade tí wọ́n fi síta yìí ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹta, ọdún 2024 ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà aadọrun àti méje ó lé igba, wọ́n pín ín ní ọ̀nà ẹẹdẹgbẹrin àti mẹ́fà, wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀na ẹẹdẹgbẹta àti ọgọ́rin ó lé ọkàn, wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ọ̀nà ọgọsan ó lé ní ìkan.
Advertisement
Nínú fídíò bíi ìṣẹ́jú kan yìí, eruku iná bo ọkọ̀ ojú omi lórí omi nígbà tí eruku dúdú ń fẹ́ kiri ojú òfuurufú.
“Ǹjẹ́ eléyìí dára?” arákùnrin kan ni ó bèrè ọ̀rọ̀ yìí léraléra nínú fídíò yìí nígbà tí iná náà ń jó.
“Wòó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ epo ni ó ń jó yìí. Àwọn nǹkan tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa rèé ní ọdọọdún. Àwọn ènìyàn rò pé a máa ń gbádùn. Inú wa kò dùn.”
Gẹ́gẹ́bí @EmekaGift100 ṣe wí, àwọn sójà ni wọ́n dáná yìí láti lè jó àwọn ọmọdé, obìnrin” láàyè.
Advertisement
Somto Okonkwo, ẹlòmíràn tí ó ń lo X tún sọ ọ̀rọ̀ naa. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn sójà máa ń mọọmọ ṣe ohun tí kò yẹ sí àwọn ará gúúsù Nàìjíríà, wọ́n sì máa ń dá ààbò bo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní àríwá Nàìjíríà.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún àti mẹtalelọgbọn àti ẹgbẹ̀ta ló ti wo fídíò yìí. Àwọn ènìyàn ẹgbẹfa ló fẹ́ràn ẹ, àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún mẹta ó dín ní mẹrindinlọgọta ló sọ̀rọ̀ nípa ẹ. Àwọn ènìyàn mẹrindinlaadọọrun ló fi àmì idankanmọ sí ojú skirini ẹ̀rọ alagbeka wọn kì wọ́n lè ríi ká nígbà miran.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YII
TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe àyẹ̀wò fídíò yìí láti lè mọ bóyá òótọ́ ni. A ríi pé àwọn ènìyàn tí fi fídíò yìí sórí Tiktok, eléyìí tí ó jẹ́ ohun ìgbàlódé tí àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán nkan láti mú inú àwọn ènìyàn dùn ní oṣù kìíní, ọdún 2024, eléyìí tí ó jẹ́ bíi oṣù méjì kí wọ́n tó pá àwọn sójà ní ìpínlẹ̀ Delta.
Advertisement
Nígbà tí wọ́n fi fídíò yìí síta, àwọn ènìyàn sọ pé ìjàmbá iná tí ó ṣẹlẹ̀ ní Nembe Waterside, ní Port-Harcourt, olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers, ni ó fà á.
“Ìjàmbá iná mìíràn ní Nembe Waterside, tí kò jìnnà sí creek road ní Port-Harcourt, tún ti ṣẹlẹ̀,” àkòrí fídíò yìí ló wí báyìí.
Advertisement
Fídíò yìí ní àwọn nǹkan bíi ọ̀rọ̀ abẹlẹ àti àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀. Àwọn nǹkan yìí náà wà nínú fidio tí wọ́n fi síta lórí Twitter lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n pa àwọn sójà ní Delta.
Àyẹ̀wò tí a tún ṣe síwájú gbé ìròyìn kan jáde tí ó fi yé wa pé fídíò yìí jẹ́ fídíò ìjàmbá iná tí ó ṣẹlẹ̀ nínú oṣù kìíní, ọdún 2024, tí ó ba àwọn nǹkan kan àti àwọn dúkìá jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Rivers.
Advertisement
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Irọ́ ni fídíò tí ó sọ pé iná ń jó Okuama.
Advertisement
Add a comment