--Advertisement--

Rárá, òògùn parasitamọ kò ní machupo virus

Ọ̀rọ̀ kan tí àwọn ènìyàn ń pín lórí  ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọ̀rọ̀ (WhatsApp) ti gba àwọn ènìyàn ní amọran kí wọ́n má lo òògùn parasitamọ tí ó ní lẹta P àti nọ́mbà ẹẹdẹgbẹta. 

“Sọra. Má lo parasitamọ tí wọ́n kọ P-500 sára rẹ̀. Ó jẹ́ parasitamọ tuntun tí ó ń dán. Àwọn dọkita sọ pé ó ní “machupo” virus (kòkòrò àrùn), eléyìí tí wọ́n ní ó burú, tí ó sì lè ṣekú pani/pa ènìyàn,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe wí.

Lẹ́hìn WhatsApp, a rí ọ̀rọ̀ yìí ní ori ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọ̀rọ̀.

Advertisement

“Ẹ jọ̀wọ́ pín ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ mọ̀ àti àwọn ẹbí yín, kí ẹ sì rán wọn lọ́wọ́ láti wà láyé…mo ti ṣe ohun tí Ọlọ́run rán mi. Ẹ̀yin ló kàn. Ẹ rántí pé àwọn tí ó bá ran ara wọn lọ́wọ́ ni Ọlọ́run máa ń ràn lọ́wọ́. Ẹ pín ọ̀rọ̀ yìí,” bí ọ̀rọ̀ ohun ìgbàlódé ibaraẹnisọ̀rọ̀ yìí ṣe wí nìyí.

Ọ̀rọ̀ yìí kò sọ fún wa bóyá wọ́n bèèrè lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ nípa iṣẹ́ ìlera tàbí àwọn tí ó ń po òògùn kí wọ́n tó parí ọ̀rọ̀ yìí.

Advertisement

Egbògi parasitamọ jẹ́ òògùn tí a máa ń lò fún ara ríro. Àwọn dọkita máa n sọ pé kí àwọn tí ara bá ń ro tàbí ní ibà lo. Iye tí wọ́n máa ń ní kí àwọn àgbàlagbà lò ni ẹẹdẹgbẹta miligraamu tàbí graamu kan.

Machupo jẹ́ virus tí àwọn ènìyàn máa ń kó láti ara ẹran. Wọ́n tún máa ń pèé ní black typhus tàbí Bolivian hemorrhagic fever.

Àwọn ènìyàn kọ́kọ́ mọ̀ nípa ẹ ní ọdún 1959 ní orílẹ̀-èdè Bolivia. Orílẹ̀-èdè yìí tí ó wà ní South America (Gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà) nìkan ni virus yìí tí ṣẹlẹ̀.

Gẹ́gẹ́bí Stanford Unifasiti ṣe wí, virus yìí máa ń tán ká lára nkan jíjẹ àti àwọn ohun tí a bá fi ara kàn tàbí fi ara kó.

Advertisement

Ǹjẹ́ virus yìí wa nínú parasitamọ?

ISARIDAJU

Ayẹwo tí TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára se fi yé wa pé àwọn ènìyàn tí ń pín ọ̀rọ̀ yìí kiri láti ọdún 2017. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi tí àwọn ènìyàn tí ń pín ọ̀rọ̀ ni wọ́n ti sọ pé irọ́ ni.

Ní ọdún 2017, àwọn eleto ìlera tí orílẹ̀-èdè Malaysia sọ pé kìí ṣe òótọ́.

Advertisement

Malaysia fi kún-un pé àwọn kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kankan nípa parasitamọ tí ó ní virus tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó mọ nípa òògùn ṣíṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Ní ọjọ́ keje, oṣù karùn-ún, àjọ tí ó ṣàkóso ọ̀rọ̀ ìlera ní orílẹ̀ èdè Zambia sọ pé ọ̀rọ̀ yìí tí àwọn ènìyàn ń pín lórí àwọn ohun ibaraẹnise kìí ṣe òtítọ́. Wọ́n fi kún un pé parasitamọ kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú virus yìí.

Advertisement

Nonso Odili, onímọ̀ bí a ṣe ń po egbògi/òògùn tí ó tún jẹ́ ọga ilé iṣẹ́ tí a mọ̀ sí DrugIT sọ fún TheCable pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.

“Eléyìí tí pẹ. Ìgbà kan wà bí ọdún díẹ̀ sẹhin tí àwọn ènìyàn ti ń pín ọ̀rọ̀ yìí kiri. Ní ìgbà yìí, wọ́n sọ pé irọ́ ni.

Advertisement

“Ní ìgbà yẹn, WHO-World Health Organization, àjọ àgbáyé tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìlera àti NAFDAC-National Agency for Food and Drug Administration and Control, àwọn tí ó ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ oúnjẹ àti òògùn ní Nàìjíríà kò sọ nkankan nípa ẹ, bóyá nítorí pé kò tó nkan tí ó tó sọ nkan nípa ẹ,” èyí ni èsì Nonso.

“Ó ṣe kókó kí àwọn ènìyàn máa lo oògùn tàbí àwọn ohun tí NAFDAC lọ́wọ́ sí.”

Advertisement

Nígbà tí ó ń dáhùn sì ọ̀rọ̀ yìí, Olusayo Akintola, agbẹnusọ fún NAFDAC sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ohun tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ kà sí nítorí pé kò sí aridaju ayẹwo kankan láti laabu (laboratory).

BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÍ SÍ

Ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn sọ pé parasitamọ tí ó ní lẹta P àti nọ́mbà ẹẹdẹgbẹta lára ní machupo virus nínú kìí se òótọ́.

Àwọn ènìyàn ti pin-in ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè. Irọ́ gbáà ni.

Add a comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

error: Content is protected from copying.