Victor Osimhen jẹ́ ẹni tí ìgbábọ́ọ̀lù rẹ̀ wú ni lórí nínú ìdíje eré bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá tí ó ń wáyé lọ́wọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè Afíríkà (aláwọ̀ dúdú) tí a mọ̀ sí Africa Cup of Nations (AFCON) ní èdè òyìnbó. Ìdíje náà ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Ivory Coast. Biotilẹjẹpe góòlù kan ni ó ti jù sí àwọ̀n nínú ìdíje náà, arákùnrin gbajúgbajà náà ti kópa gidi nínú ìlàkàkà àwọn àgbàbọ́ọ̀lù àgbà (Super Eagles) fún Nàìjíríà.
Ó jẹ́ alátìlẹ́yìn fún àwọn Super Eagles. A sì rí ipa tí ó kó nígbà sáà kejì nígbà ìgbàbọ́ọ̀lù pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Cameroon. Òhun ni ó jẹ́ kí àwọn àgbàbọ́ọ̀lù Nàìjíríà fi ìdí Cameroon, tí a tún mọ̀ sí Indomitable Lions rẹmi pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo (2-0).
Àgbàbọ́ọ̀lù náà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún marundínlọgbọn kò jìnnìjìnnì bá àwọn ọmọ Cameroon, pẹ̀lú bí ó ṣe ń lé bọ́ọ̀lù tí àwọn ọmọ Cameroon bá jẹ́ kó bọ́ ṣílẹ̀.
Àgbàbọ́ọ̀lù náà, ẹni tí ó ti gba ìdánimọ̀ àgbàbọ́ọ̀lù tó yanrantí (African footballer of the year), ní ọdún 2023, ran Ademola Lookman, àgbàbọ́ọ̀lù ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́.
Advertisement
Lẹ́hìn ipa tí ó kó yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ohun ìgbàlódé ìbáraẹnise (social media) ti ń pín fídíò ẹni tí wọ́n rò pé “Osimhen” ni níbi tí ó ti ń tíréènì.
Nínú fídíò yìí, ẹni tí ó wà nínú rẹ̀ tí ó jọ Osimhen ń tíréènì pẹ̀lú táyà, shéènì àti ǹkan tí a fi ǹkan rẹ́.
“O fẹ́ mọ ìdí tí Osimhen fi ní agbára tí ó jẹ́ kí ó lè figagbága pẹ̀lú àwọn àgbàbọ́ọ̀lù ẹgbẹ́ rẹ̀? Wò ó ní ibi tí ó ti ń tíréènì,” Nkirukamma, olùmúlò ohun ìbáraẹnise alámì krọọsi (X, formerly known as Twitter) ti orí ayélujára, kọ èyí bí àkòrí fídíò tí ó fi síta.
Advertisement
Atẹjade yìí tí ní àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọọdunrun ó dín ní mẹsan tí ó wòó/ríi. Ẹgbẹ̀rún púpọ̀ ènìyàn ní wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì pín-ín lórí ohun ìbáraẹnise alámì krọọsi.
Àwọn ènìyàn tún pín fídíò yìí lórí àwọn ohun ìbáraẹnise mìíràn bí wọsapu (whatsapp).
You want to know why Osimhen shows so much strength in duels with fellow footballers?
Watch his physical training!👍🏿 pic.twitter.com/hZjOr1Ljvt
Advertisement— Nkirukamma (@SabinaNkiru) January 31, 2024
King Osimhen, training like a beast using orthodox methods for high effect!
Why won’t CAF call him for a drug test 😂Bro went beast mode!
Bro took his training back to the ibile ways!AdvertisementRASHFORD!!!!!
What’s your excuse?#AFCON2023 #AFCON pic.twitter.com/41PTNKA0e9— 44.Yommie 🗽 (@itsYomi) February 1, 2024
Advertisement
Victor Osimhen the buster… Training to devour Angola pic.twitter.com/4Zbqb24kkf
Advertisement— Kingsnetwork (@Kingsnetswork) January 29, 2024
Advertisement
ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ
TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára tọ pinpin ibi tí fídíò yìí ti wá. A ríi pé Ebube David, ẹni tí ó máa ń fi àwọn ǹkan tí àwọn ènìyàn máa fẹ́ràn sí orí ayélujára ni ó fi sí orí ayélujára.
David, ẹni tí ó wà nínú fídíò yìí tí ó ń tíréènì pẹ̀lú shéènì àti táyà àlòkù ní àwọn ènìyàn tí ó ju igba dín ní mẹ́wàá ẹgbẹ̀rún tí wọ́n ń tẹ̀ lée ní orí TikTok, orí ohun ìgbàlódé ìmúnilárayá orí ayélujára tí àwọn ènìyàn tí máa ń múnú àwọn ènìyàn dùn.
Ó fi fídíò náà síta ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2023, pẹ̀lú àkòrí tí ó wí pé: “Victor Osimhen ṣe iṣẹ́ kárakára láti lè ṣe orire, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.”
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ
Ẹni tí ó wà nínú fídíò yìí kìí se Victor Osimhen. Ebube David ni ó wà nínú fídíò yìí.
Ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé Osimhen ni ó wà nínú fídíò yìí kìí se òótọ́.
Irọ́ gbáà ni.
Add a comment