Fídíò kan tí Bill Gates wà nínú rẹ̀ nígbà tí wọn ṣe ifọrọwani-ni-ẹnuwo pẹ̀lú rẹ̀ lórí ẹ̀rọ amohunmaworan orílẹ̀-èdè Australia tí a mọ̀ sí Australian Broadcasting Corporation (ABC) News ni àwọn ènìyàn ti se àyípadà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rọ ìgbàlódé, tí wọ́n sì pa irọ́ lórí ọrọ abẹrẹ (vaccine) àti maikrosọfti (Microsoft).
Àwọn ènìyàn pín fídíò yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ lórí ẹ̀rọ abẹyẹfo (Twitter) àti ẹ̀rọ tí a ti ń pín àwòrán ara ẹni (Instagram).
Olumulo ẹ̀rọ náà tí a mọ̀ sí @meekystudios pin fídíò náà pẹ̀lú àkòrí: “eléyìí ya ni lẹ́nu, níbo ni arábìnrin yìí tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ tí ó pé ojú òṣùwọ̀n ti wà tí ó mú Bill Gates, ẹni tí ó lowo jù ni gbogbo àgbáyé tẹ́lẹ̀rí tí ó fi ń fikan pe méjì.”
Àwọn ènìyàn fẹ́ràn atẹjade náà ní ọna ẹgbẹ̀rún méjìdínlọgbon àti ọgọ́rùn-ún, wọn sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọna ẹgbẹ̀ta àti mẹ́rìnlá. Wọn s’atunpin rẹ̀ ní ọna ẹgbẹfa àti mẹ́ta.
Advertisement
Olumulo míràn tí a mọ̀ sí @fqryonline s’atunpin fídíò náà lórí ẹrọ tí àwọn ènìyàn tí ń pín àwòrán ara wọn. Àwọn ènìyàn fẹ́ràn fídíò náà ní ọna tí ó ju ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún. Wọn pín in ní ọna ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín mẹjọ.
Nínú fídíò náà, Sarah Ferguson, onisẹ ìròyìn ń fi ọ̀rọ̀ wá Bill Gates, oludasilẹ maikrosọfti lẹnuwo.
“Arákùnrin Gates, kí ni ó ti gbé ṣe fún àgbáyé?”, ó dàbí pé arábìnrin náà bi.
Advertisement
“N kò lérò pé ó mọ̀. Amọsa, èmi ni mo dá òun tí a fi máa ń lo kọnputa (computer operating system) silẹ.” O dàbí pé Gates fèsì báyìí
Lẹ́hìn ìgbà tí wọ́n fi ẹ̀sùn jiji nkan tí wọn fi máa ń lo kọnputa kan, olufiọrọwani-ni-ẹnuwo náà bèrè àwọn ìbéèrè tí ó ń mú ara fi ẹni lórí àrùn kofiidi (Covid19), ní ọna tí ó fi yé wa pé Gates jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ abẹrẹ.
Ohùn kan tí ó dàbí tí olufiọrọwani-ni-ẹnuwo tún se ìbéèrè pé: “ìwọ ti jẹ́ agbẹnusọ nípa abẹrẹ kofiidi nígbà ajakalẹ àrùn yìí, kí ni ìdí gangan tí ó jẹ́ kí ìwọ tí o jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ kọnputa tí kò ṣe agbekalẹ ètò isẹ ọwọ rẹ̀ fi di agbẹnusọ àwọn tí ó ń po òògùn?”
Atẹjade náà fi yé wa pé Gates fèsì pé “mo ti ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé nípa ọ̀rọ̀ yìí, mo sì ti rí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yii káàkiri àgbáyé,” ohùn Gates ni ó dàbí pé ó fèsì.
Advertisement
Ni ìparí ifọrọwani-niẹnuwo náà, àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn arábìnrin afọrọwanilẹnuwo náà bí ó se bèrè nípa ìwà tó kudiẹkaato tí ó jẹ́ kí Gates máa jí àwọn ohùn ẹ̀rọ kọnputa tí ó le tí “kò yé e, tí ó sì ta ohùn ẹ̀rọ kọnputa tí ó pani lára, tí ó sì ba nkan jẹ́ tí ó sì rí èrè yanturu nínú rẹ̀.”
ISARIDAJU
Nígbà tí a ka àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí lórí àwọn ohùn ibaraẹnise tí ìgbàlódé níbi tí wọn ti pín ọ̀rọ̀ náà, a ríi pé àwọn tí wọn wòó tàbí ríi kò mọ̀ pé wọn yí ọ̀rọ̀ náà padà.
Olumulo àwọn ohùn ibaraẹnise tí ìgbàlódé kan tí ó ti rí ifọrọwani-niẹnuwo gidi yìí pé àkíyèsí àwọn ènìyàn sì ọ̀rọ̀ náà pé fídíò yìí tí ó jẹ́ gidi kò ní ọ̀rọ̀ nípa abẹrẹ kofiidi àti maikrosọfti nínú.
Advertisement
Ìwé ìròyìn TheCable fi kókó ọ̀rọ̀ inú fídíò náà ṣe ayẹwo rẹ̀. A ríi fídíò gidi ọ̀rọ̀ náà tí ilé isẹ ìròyìn amohunmaworan ABC ti orílẹ̀-èdè Australia gbé jáde tí wọn pè ní “7.30”
Advertisement
Ayẹwo TheCable fi yé wa pé kò sí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn s’atẹjade tàbí s’atunpin nínú fídíò yii tí ó jẹ́ gidi.
Nínú ifọrọwani-niẹnuwo gidi nípa ọ̀rọ̀ yìí tí a rí, afọrọwani-ni-ẹnuwo tí ó ṣeé mẹ́nuba àyípadà wẹda, sise iranlọwọ fún àwọn ènìyàn, sísọ ọ̀rọ̀ tí kìí se òtítọ́ àti wàhálà tí ajakalẹ àrùn míràn lè fà àti ajọjẹ Gates pẹ̀lú arákùnrin Jeffrey Epstein.
Advertisement
Nígbà tí TheCable tún se ayẹwo fídíò náà síwájú sí, a ríi wí pé ifọrọwani-niẹnuwo náà tí ó jẹ́ ohùn lásán kò jọ ohùn afọrọwani-ni-ẹnuwo arábìnrin Ferguson àti Gates.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ SÌ
Advertisement
Àwọn ènìyàn tí ṣe àyípadà sì fídíò tí wọn ń pín kiri yìí. Wọn sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ irọ́ kún un. Fídíò ọ̀rọ̀ náà tí ó jẹ́ gidi yàtọ̀ sí èyí tí àwọn ènìyàn fi irọ́ púpọ̀ kún.
Add a comment