Peter Obi, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra tẹ́lẹ̀rí, ẹni tí ó jẹ́ Adijedupo fún Ipò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òsèlú àwọn òṣìṣẹ́ (Labour Party-LP) sọ oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ nígbà tí ó ń ṣe agbekalẹ ètò rẹ̀ fún ọ̀rọ̀ ajé/karakata ní ibi ifiọ̀rọ̀jomitoroọ̀rọ̀ fún àwọn tí ó ń díje fún Ipò Ààrẹ, tí Nigerian Economic Summit Group (NESG) ṣe àpéjọ rẹ̀.
Ìwé ìròyìn TheCable se ìwádìí àwọn ọ̀rọ̀ náà láti mọ̀ bóyá déédéé bí ó se wí ní wọn rí.
Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́: Ọ̀rọ̀ ajé bí a ṣe ńṣe nkan tí àwọn ènìyàn ń lò ni ó ń fún wa ní idamẹwa owó tí ó wọlé.
Bí a ṣe rí ọ̀rọ̀ náà sì: Òtítọ́ ni.
Advertisement
Atẹjade/Ìfitónilétí àjọ tí ó ń se ètò kika nkan (National Bureau of Statistics-NBS) fún osù keje sí oṣù kẹsàn-án tí ọdún 2022 fihàn pé ọrọ̀ ajé bí a ṣe ńse nkan fún wa níbi ìdá mẹsan owó tí a rí.
Iye yìí dín sí ìyè idamẹsan ó dín díẹ̀ tí a rí nípa ṣíṣe nkan láàárín osù keje sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2021 àti ìdá mẹ́sàn-án ó dín díẹ̀ tí a rí láàárín osù kẹrin si osù kaarun/kẹfà, ọdún 2022.
Ọ̀rọ̀ kejì: Àwọn oun tí a ń rí ní ara iṣẹ́ agbẹ/oun ọgbin ni ó ń fún wa ní ìdá mẹrindinlọgbọn nínú owó tí ó ń wọlé.
Advertisement
Ìwádìí wa: Eléyìí kìí se òtítọ́.
Ìdá ní ọna ọgbọ́n ó dín díẹ̀ ni owó tí iṣẹ́ agbẹ ń fún wa nínú gbogbo owó tí a rí láàárín osù keje sí osù kẹjọ/kẹsàn-án, èyí tí ó din díẹ̀ sì iye tí ó wọlé ní osù keje sí osù kẹjọ/kẹsàn-án, ọdún 2021.
Tí a bá wo data àjọ NBS fún osù keje sí osu kẹjọ/kẹsàn-án, ọdún 2022, owó tí a rí lára àwọn oun ọrọ̀ ajé tí kìí se epo rọbi fún wa ní bíi ìdá mẹ́fà ó dín díẹ̀, èyí tí ó dín ní ìdá méje ó lé díẹ̀ tí a rí láàárín osù keje sí osù kẹjọ/kẹsàn-án, ọdún 2021, ìdá mẹ́fà ó lé díẹ̀ tí a rí láàárín osù kẹrin sí osù kaàrún/kẹfà, ọdún 2022.
Ọ̀rọ̀ kẹta: Àwọn tí kò rí iṣẹ́ se ní orílẹ̀-èdè Kenya jẹ́ idamẹwa àwọn ènìyàn ìlú náà.
Advertisement
Ìwádìí wa: Òtítọ́ ni èyí.
Data tí a tẹjade làti ọwọ́ Statista àti Macrotrends laipẹ yìí nínú ọdún 2021 fi yé wa pé iye àwọn ènìyàn tí kò rí iṣẹ́ se ní Kenya jẹ́ ìdá mẹ́fà ó dín díẹ̀ nínú gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìlú náà.
Àwọn tí kò rí iṣẹ́ se jẹ́ àwọn tí ó setan láti se iṣẹ́, tí wọ́n sì ń wá iṣẹ́.
Ní ọdún 2020, iye àwọn ènìyàn yìí jẹ ìdá mẹ́fà ó dín díẹ̀ àwọn ènìyàn ìlú náà, ìdá márùn-ún ó lé díẹ̀ ní ọdún 2019 àti ìdá mẹ́rin ó lé díẹ̀ ní ọdún 2018.
Advertisement
Láàárín ọdún 2003 àti ọdún 2016, iye àwọn ènìyàn tí kò rí iṣẹ́ se dín ní ìdá mẹwa ni Kenya.
Ọ̀rọ̀ kẹrin: Ilẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Netherlands wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọna ọgbọ́n àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kìlómítà.
Advertisement
Bí a ṣe rí ọrọ náà sí: Òtítọ́ ni èyí.
Bánkì fún àgbáyé (World Bank) sọ wí pé gbogbo ilẹ̀ tí Netherlands wá lórí rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọna ọgbọ́n àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín díẹ̀.
Advertisement
Ọ̀rọ̀ kaarun: Àwọn èrè iṣẹ́ ọgbin/agbẹ tí Netherlands kó lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn fún títa jẹ́ ọgọfa biliọnu dọla ní ọdún 2021.
Àbájáde Ìwádìí wa: Ọ̀rọ̀ yìí kìí se òtítọ́/òótọ́.
Advertisement
Gbogbo owó tí iye èrè iṣẹ́ ọ̀gbìn tí Netherlands tá ní orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ aadoje biliọnu ó lé ní ẹẹdẹgbẹrin mílíọ̀nù dọla kìí se ọgọ́fà biliọnu dọla.
Netherlands pín àwọn èrè isẹ agbẹ tí wọn ń kó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn sí ọna méjì. Àwọn ọna méjì náà ni àwọn oun tí ó jọ mọ́ àwọn oun nkan ọ̀gbìn àti àwọn oun ọgbin.
Àwọn oun tí ó jọ mọ́ oun ọgbin ni àwọn oun tí kìí se jíjẹ tí a ṣe fún títa ní Netherlands tàbí tí a se láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn fún títa.
Àwọn nkan ọgbin ni àwọn nkan tí a ko lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn fún títa tabi sọdi nkan mìíràn ni Netherlands.
Gẹ́gẹ́bí data 2021 fi yé wa, gbogbo iye àwọn èrè nkan tí a gbìn tí a kó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn fún títa jẹ́ ọgọ́fà àti méjì biliọnu uro (owó ilẹ̀ uropu) èyí tí ó jẹ́ aadoje biliọnu ó lé ẹẹdẹgbẹrin mílíọ̀nù dọla.
Iye owó àwọn oun ọ̀gbìn tí ó lè ṣe jẹ jẹ́ bíi ọgọ́rùn-ún àti mẹ́fà biliọnu uro nígbà tí àwọn oun tí kò ṣeé jẹ jẹ́ biliọnu mẹ́rìndínlógún uro.
Ọ̀rọ̀ kẹfà: Mo mọ̀ wí pé Amẹ́ríkà, orílẹ̀-èdè tí ó ní owó jùlọ jẹ gbèsè tí ó tó ìdá àádọ́rùn-ún iye owó tí wọn ń rí/ní. Orílẹ̀-èdè China jẹ gbèsè tí ó tó ìdá ọgọ́ta iye owó tí wọn ni/ó wọlé fún wọn, gbèsè orílẹ̀-èdè Japan jẹ́ idà òjìlénígba ó dín mẹwa iye owó tí ó wọlé fún wọn.
Orílẹ̀-èdè Singapore tí a máa fi ń se àpèjúwe ní ojoojumọ jẹ gbèsè tí owó rẹ tó ìdá aadoje owó tí ó ń wọlé fún wọn. Ìṣòro tí a ní ni wí pé a kìí rí owó tí a yá.
Àbájáde ìwádìí: Irọ́ ni.
Biotilẹjẹpe àyẹ̀wò tí ìwé ìròyìn TheCable se fihàn pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mẹrin tí Obi sọ̀rọ̀ nípa wọn jẹ gbèsè, amọsa, ọ̀rọ̀ tí arakunrin Obi sọ yìí kìí se òtítọ́.
Àwọn atẹnkanjade kan tí a mọ̀ sí Investopedia sọ wí pé iye gbèsè sì owó tí ó ń wọlé/tí orílẹ̀-èdè kan ní jẹ gbèsè orílẹ̀-èdè náà sí iye owó tí wọn ní/tí ó wọlé fún wọn.
Bí a ṣe máa ń mọ nkan tí a ṣe àlàyé rẹ lókè yìí ni wí pé a máa ń wo iye gbèsè tí orílẹ̀-èdè kan jẹ sí iye àwọn nkan tí wọn ńse fún títa. Ó tún máa ń jẹ kí a mọ iye ọdún tí orílẹ̀-èdè kan yóò fi san gbèsè rẹ tán.
Orílẹ̀–èdè Amẹ́ríkà
Iye gbèsè tí Amẹ́ríkà jẹ jẹ́ ìdá ọgọ́fà àti mẹrin owó tí wọn ní kii se ìdá àádọ́rùn-ún tí Obi sọ.
Fiscal Data, àwọn kan tí ó ń se atẹjade ní orí ayelujara tí ó se ayẹwo àwọn onka fún ọrọ̀ ajé se àlàyé pé gbèsè tí Amẹ́ríkà jẹ jẹ́ ìdá ọgọ́fà àti mẹrin iye owó wọn tí a bá wo rẹkọọdu ọdún 2022.
Ní ọdún 2013, gbèsè Amẹ́ríkà kọjá ìdá ọgọ́rùn-ún nígbàtí gbèsè tí wọn jẹ sí iye owó tí wọn ní jẹ bíi triliọnu mẹ́rìndínlógún àti ẹẹdẹgbẹrin biliọnu dọla.
China
Ní ìparí ọdún 2022, gbèsè tí China jẹ jẹ́ ìdá mẹrindinlaaadọrin iye owó tí wọn ní, kìí se ìdá ọgọ́ta tí Obi sọ.
Japan
Nínú osù kẹsàn-án, ọdún 2022, gbèsè orílẹ̀-èdè Japan jẹ́ ìdá ọgọta-leni-igba àti díẹ̀ sí iye owó tí wọn ní, kìí se ida igba àti ọgbọn tí Obi sọ.
Nọ́mbà tí ọdún 2022 lé síi ni láti ìdá ọgọta-leni-igba ó dín díẹ̀ tí ó jẹ́ ní ọdún 2020 nígbà ajakalẹ àrùn kofiidi (Covid19 outbreak).
Singapore
Atẹjade àjọ tí ó ń ya àwọn orílẹ̀-èdè lowo (International Monetary Fund-IMF) sọ wí pé gbèsè tí orílẹ̀-èdè Singapore jẹ jẹ́ ìdá ogoje àti ìkan ó lé díẹ̀, kìí se ìdá aadoje tí Obi sọ.
Ọ̀rọ̀ Keje: Gbèsè tí Nàìjíríà jẹ jẹ́ ẹẹtadinlọgọrin triliọnu náírà.
Bí a ṣe rí ọ̀rọ̀ náà sí: Irọ́ ni.
Lọ́wọ́lọ́wọ́, gbèsè tí Nàìjíríà jẹ jẹ́ ẹẹrinlelogoji triliọnu àti ọgọ́ta biliọnu náírà, kìí se ẹẹtadinlọgọrin triliọnu naira.
Àjọ tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ gbèsè Nàìjíríà (Debt Management Office-DMO) se atẹjade iye gbèsè tí Nàìjíríà jẹ ní aipẹ yìí ní osù kẹsàn-án, ọdún 2022.
Atẹjade náà sọ pé gbèsè Nàìjíríà tí a bá pá gbogbo gbèsè ìjọba Àpapọ̀, àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀ àti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ pọ̀ jẹ́ triliọnu mẹrinlelogoji àti ọgọ́ta biliọnu naira.
Aropọ gbèsè àwọn Ìpínlẹ̀, ti Abuja, tí ó jẹ Ólù ìlú Nàìjíríà àti ti ìjọba Àpapọ̀ ni ó fún wa ní iye gbèsè náà.
Iye tí Nàìjíríà jẹ àwọn ayanilowo ni Nàìjíríà jẹ triliọnu mẹtadinlọgbọn ó dín ní ẹgbẹrin biliọnu náírà. Gbèsè tí Nàìjíríà jẹ àwọn ayanilowo ní orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ triliọnu mẹtadinlogun àti ogoje biliọnu náírà.
Amọsa, Patience Oniha, ẹni tí ó jẹ́ ọga pátápátá fún àwọn àjọ tí ó ń rí sí ọrọ gbèsè sọ wí pé ètò kan tí àwọn n se lọ́wọ́ yóò jẹ́ kí gbèsè náà lé síi tó ẹẹtadinlọgọrin triliọnu náírà.
Èyí túmọ̀ sí pé ìjọba mìíràn tí a má fi ìbò yàn yóò bá gbèsè triliọnu ẹẹtadinlọgọrin náírà nilẹ lẹ́hìn tí Ìjọba Ààrẹ Buhari bá parí ní osù kaarun, ọdún yìí.
Ọ̀rọ̀ kẹjọ: Iye àwọn nkan tí Nàìjíríà kó lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn fún títa ní ọdún 2021 jẹ́ triliọnu mọkandinlogun ó dín ní ọgọrun bíliọnu náírà.
Àbájáde Ìwádìí: Òtítọ́ ni.
Data nípa àwọn nkan tí a kó lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè kan fún títa tí Bánkì Àpapọ̀ Nàìjíríà (Central Bank of Nigeria-CBN) gbé jáde fi yé wa pé ní ọdún 2021, iye gbogbo owó tí àwọn nkan tita tí a ko lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè kan jẹ́ biliọnu mẹtadinlaaadọta ó din ní ọọdunrun àti mẹwa mílíọ̀nù dọla, èyí tí ó lé ju biliọnu mẹrindinlogoji ó dín ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọla tí owó nkan ọrọ̀ ajé tí a ko lọ fún títa ní òkè òkun jẹ́ ní ọdún 2020.
Ìwé ìròyìn TheCable tún se ayẹwo data NBS lórí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
Eléyìí fi yé wa pé owó àwọn ọjà tí a ko lọ sí òkè òkun tó triliọnu mọkandinlogun ó dín ní ọgọ́rùn-ún biliọnu náírà ní ọdún 2021, eléyìí tí ó jẹ biliọnu mẹtadinlaaadọta àti ọọdunrun mílíọ̀nù náírà tí a ba wo iye tí a fi paarọ owó náírà sì àwọn owó orílẹ̀-èdè mìíràn tí a bá lo bí irínwó náírà tí Ìjọba lọ́wọ́ sí gẹ́gẹ́bí owó tí a lè fi se pasiparọ fún owó àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní ọdún 2021.
Add a comment