Ẹniọlá Badmus, òṣèré gbajúmọ̀ ti sọ pé biotilẹjẹpe ìjọba Nàìjíríà ti yọ owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún epo pẹtiroolu tí ó sì jẹ́ kí owó lítà epo kan lé ju owó tí wọ́n ń tàá tẹ́lẹ̀, iye tí Nàìjíríà ń ta epo pẹtiroolu ló kéré jù ní àgbáyé.
Òṣèré náà, ẹni tí ó jẹ́ gbajúgbajà alátìlẹ́yìn Ààrẹ Bọla Tinubu, sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi tí wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ wáa lẹ́nu wò lórí ohun ìgbàlódé ibaraẹnise tí àwọn ènìyàn ti ń pín àwòrán wọn tí Daddy Freeze, ẹni tí ó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká agbohunsafẹfẹ ṣe.
Badmus sọ wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ pé ìjọba Tinubu sedakoseda kò mọ àǹfààní owó kiaramabani àwọn ènìyàn tí Tinubu yọ yìí.
“Gẹ́gẹ́bí ọmọ orílẹ̀-èdè yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti lè sọ ọ̀rọ̀ bí mo ṣe rò. Mo lè ṣe atilẹyin fún ẹni tí mo bá fẹ́,” arábìnrin yìí ni ó sọ báyìí.
Advertisement
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó jẹ́ wí pé orí ayélujára nìkan ni wọ́n ti máa ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò ti ẹ̀ mọ ohun tí owó kiaramabani àwọn ènìyàn jẹ́. Ìgbà tí Ìjọba yọọ́ ni wọ́n tó mọ nkan tí Ìjọba ń ṣe. Títí di àsìkò yìí, mo rò pé àwa ló sìí ń ra epo pẹtiroolu ní iye tí owó rẹ̀ kéré jù ní àgbáyé.
“Mímí kan kò lè mi Ààrẹ Tinubu. Lẹ́hìn pé mò ń ṣe atilẹyin fún un, mo ti rí nkan tí ó ti ṣe. Mo sì mọ ohun tí yóò ṣe. N kò tíì rí onínúrere, afunnimawobẹ, oluranlọwọ àwọn aláìní bíi ti Ààrẹ wa yìí. N yóò ṣe àtilẹyin fun títí yóò fi kúrò ní ipò Ààrẹ.
YÍYỌ OWÓ KIARAMABANI ÀWỌN ÈNÌYÀN FÚN PẸTIROOLU
Advertisement
Ní ọjọ́ kọkàndínlógún, ọdún 2023, Ààrẹ Tinubu nígbà tí ó ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lẹ́hìn tí wọ́n ṣe ìbúra fún un tán gẹ́gẹ́bí Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà sọ wí pé òpin ti dé bá owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún epo pẹtiroolu.
“Nípa owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún epo pẹtiroolu, ètò owó níná tí ó wà ní ilẹ̀ kí n tó di Ààrẹ ní wí pé kò sí agbekalẹ kankan fún owó kiaramabani àwọn ènìyàn fún epo pẹtiroolu. Nípa ìdí èyí, òpin ti dé bá owó yìí,” Tinubu ni ó wí báyìí.
Ó fikùn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò sí àlàyé tí ó munadoko tí Ìjọba lè ṣe lórí owó iyebíye tí wọ́n ń nọ́ lórí owó kiaramabani àwọn ènìyàn tí Ìjọba ń nọ́ ní gbogbo ìgbà ní àsìkò tí kò sí owó yìí.
“A gbóríyìn fún ìjọba tí ó lọ lórí owó kiaramabani àwọn ènìyàn tí wọ́n yọ, èyí tí ó ń ṣe àǹfààní fún àwọn olówó, tí ó sì ń jẹ́ kí ebi pa àwọn aláìní.
“A máa nọ́ owó tí a yọ yìí lórí àwọn ohun tí ó lè mú owó wọlé bíi ojú ọ̀nà, ètò ẹ̀kọ́, ètò ìlera àti ìpèsè iṣẹ́ àti àwọn ohun amayedẹrun fún àwọn ènìyàn púpọ̀.
Advertisement
Ní aipẹ tí Tinubu sọ ọ̀rọ̀ yìí, owó epo pẹtiroolu lọ sókè. Kí ó tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, owó lítà epo kan jẹ́ igba ó dín mẹwa náírà. Lẹ́hìn tí ó sọ ọ̀rọ̀ yìí, owó lítà kan di ẹẹdẹgbẹta náírà.
Ní ọjọ́ kejìdínlógún, àwọn alagbata epo sọ iye owó lítà kan di ẹgbẹtalelogun ó dín mẹ́ta náírà ní Abuja àti ẹẹdẹgbẹta àti àádọ́rin ó dín méjì náírà ní ìlú Èkó.
Ǹjẹ́ owó lítà epo ní Nàìjíríà ni ó kéré jù ní àgbáyé?
TheCable, ìwé ìròyìn orí ayélujára ṣe ìwádìí iye owó lítà epo kan ni àwọn oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè. Àbájáde wa rèé.
Advertisement
ÀYẸ̀WÒ OWÓ EPO NÍ ÀGBÁYÉ
Gẹ́gẹ́bí globalpetrolprices, àwọn tí wọ́n máa ń mọ iye owó pẹtiroolu, iná mọ̀nàmọ́ná àti gaasi ni àwọn orílẹ̀-èdè tó ju àádọ́jọ lọ ṣe wi, orílẹ̀-èdè Venezuela ni owó epo ti kéré jù. Iye owó lítà kan níbẹ̀ lé díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta náírà.
Advertisement
Ìwádìí tí a tún ṣe síwájú fi yé wa pé iye owó epo ní orílẹ̀-èdè ogún dín ní ẹgbẹtalelogun ó dín mẹ́ta náírà.
Lára àwọn orílẹ̀-èdè yìí ni Ìran, Libya, Algeria, Kuwait, Angola, Egypt, Turkmenistan, Malaysia, Kazakhstan, Bahrain, Bolivia, Iraq, Quartar, Azerbaijan,Russia, Oman, Saudi Arabia, Ecuador, Kyrgyzstan, and Afghanistan.
Advertisement
S/N | Country | Price in $ as of July 24 | CBN Exchange rate on July 24 | price in Naira |
---|---|---|---|---|
1. | Venezuela | 0.004 | 781.85 | 3.1274 |
2. | Iran | 0.029 | 781.85 | 22.67365 |
3. | Libya | 0.031 | 781.85 | 24.23735 |
4. | Algeria* | 0.34 | 781.85 | 265.829 |
5. | Kuwait* | 0.342 | 781.85 | 267.3927 |
6. | Angola | 0.364 | 781.85 | 284.5934 |
7. | Egypt* | 0.372 | 781.85 | 290.8482 |
8. | Turkmenistan | 0.429 | 781.85 | 335.41365 |
9. | Malaysia* | 0.448 | 781.85 | 350.2688 |
10. | Kazakhstan | 0.488 | 781.85 | 381.5428 |
11. | Bahrain | 0.531 | 781.85 | 415.16235 |
12. | Bolivia* | 0.542 | 781.85 | 423.7627 |
13. | Iraq | 0.573 | 781.85 | 448.00005 |
14. | Qatar* | 0.577 | 781.85 | 451.12745 |
15. | Azerbaijan | 0.588 | 781.85 | 459.7278 |
16. | Russia* | 0.589 | 781.85 | 460.50965 |
17. | Oman* | 0.621 | 781.85 | 485.52885 |
18. | Saudi Arabia* | 0.621 | 781.85 | 485.52885 |
19. | Ecuador* | 0.634 | 781.85 | 495.6929 |
20. | Kyrgyzstan* | 0.741 | 781.85 | 579.35085 |
21. | Afghanistan | 0.743 | 781.85 | 580.91455 |
22. | Nigeria | 0.778 | 781.85 | 608.2793 |
23. | UAE* | 0.787 | 781.85 | 615.31595 |
24. | Tunisia | 0.832 | 781.85 | 650.4992 |
25. | Bhutan | 0.845 | 781.85 | 660.66325 |
26. | Lebanon* | 0.863 | 781.85 | 674.73655 |
27. | Indonesia* | 0.864 | 781.85 | 675.5184 |
28. | Colombia* | 0.867 | 781.85 | 677.86395 |
29. | Pakistan* | 0.878 | 781.85 | 686.4643 |
30. | Argentina* | 0.924 | 781.85 | 722.4294 |
31. | Belarus* | 0.935 | 781.85 | 731.02975 |
Mọkandinlogun nínú mẹ́tàlélógún àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣe ìwádìí iye tí wọ́n ń ta epo lítà kan ni wọ́n ń tàá ní owó tí ó dín ní ẹẹdẹgbẹtalelaadọrin ó dín méjì náírà (N568), èyí tí ó jẹ́ owó lítà epo tí ó kéré jù ní Nàìjíríà.
BÍ A ṢE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÍ SÍ
Advertisement
Ọ̀rọ̀ tí Ẹniọlá Badmus sọ pé owó epo lítà kan ní Nàìjíríà ni ó kéré jù nínú owó tí wọ́n ń ta lítà kan ní àgbáyé kìí se òótọ́. Irọ́ ni.
Lọ́wọ́lọ́wọ́, orílẹ̀-èdè mọkandinlogun nínú àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ni wọ́n ń ta lítà epo ní owó tí ó dín ní ẹẹdẹgbẹtalelaadọrin ó dín méjì náírà, iye owó lítà epo kan ní ìlú Èkó.
Fún ìròyìn yìí, owó orílẹ̀-èdè miran tí a fi wo ọ̀rọ̀ yìí tàbí fiwé/ṣe pasipaarọ ni dọla kan ($1), èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹrin dín ní mọkandinlogun náírà owó Nàìjíríà gẹ́gẹ́bí Bánkì ijọba Àpapọ̀ Nàìjíríà (Central Bank of Nigeria) ṣe tẹ̀ẹ́ síta ní ọjọ́ kẹrinlelogun, oṣù keje, ọdún 2023 nígbà tí arábìnrin òṣèré yìí sọ̀rọ̀ yìí.
Add a comment